II. Sam 14
14
Joabu ṣe ètò àtipadà Absalomu
1JOABU ọmọ Seruia si kiyesi i pe, ọkàn ọba si fà si Absalomu.
2Joabu si ranṣẹ si Tekoa, o si mu ọlọgbọn obinrin kan lati ibẹ̀ wá, o si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, ṣe bi ẹniti nṣọfọ, ki o si fi aṣọ ọfọ sara, ki o má si ṣe fi ororo pa ara, ki o si dabi obinrin ti o ti nṣọ̀fọ fun okú li ọjọ pupọ̀.
3Ki o si tọ̀ ọba wá, ki o si sọ fun u gẹgẹ bi ọ̀rọ yi. Joabu si fi ọ̀rọ si i li ẹnu.
4Nigbati obinrin ará Tekoa na si nfẹ sọ̀rọ fun ọba, o wolẹ, o dojubolẹ, o si bu ọla fun u, o si wipe, Ọba, gbà mi.
5Ọba si bi i lere pe, Ki li o ṣe ọ? on si dahùn wipe, Nitõtọ, opó li emi iṣe, ọkọ mi si kú.
6Iranṣẹbinrin rẹ si ti li ọmọkunrin meji, awọn mejeji si jọ jà li oko, kò si si ẹniti yio là wọn, ekini si lu ekeji, o si pa a.
7Si wõ, gbogbo idile dide si iranṣẹbinrin rẹ, nwọn si wipe, Fi ẹni ti o pa ẹnikeji rẹ̀ fun wa, awa o si pa a ni ipo ẹmi ẹnikeji rẹ̀ ti o pa, awa o si pa arole na run pẹlu: nwọn o si pa iná mi ti o kù, nwọn kì yio si fi orukọ tabi ẹni ti o kù silẹ fun ọkọ mi li aiye.
8Ọba si wi fun obinrin na pe, Lọ si ile rẹ, emi o si kilọ nitori rẹ.
9Obinrin ara Tekoa na si wi fun ọba pe, Oluwa mi, ọba, jẹ ki ẹ̀ṣẹ na ki o wà lori mi, ati lori idile baba mi; ki ọba ati itẹ rẹ̀ ki o jẹ́ alailẹbi.
10Ọba si wipe, Ẹnikẹni ti o ba sọ̀rọ si ọ, mu oluwa rẹ̀ tọ̀ mi wá, on kì yio si tọ́ ọ mọ.
11O si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ọba ki o ranti Oluwa Ọlọrun rẹ̀, ki olugbẹsan ẹjẹ ki o máṣe ni ipa lati ṣe iparun, ki nwọn ki o má bà pa ọmọ mi; on si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, ọkan ninu irun ori ọmọ rẹ ki yio bọ́ silẹ,
12Obinrin na si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iranṣẹbinrin rẹ ki o sọ̀rọ kan fun oluwa mi ọba; on si wipe, Ma wi.
13Obinrin na si wipe, Nitori kini iwọ si ṣe ro iru nkan yi si awọn enia Ọlọrun? nitoripe ọba si sọ nkan yi bi ẹniti o jẹbi, nitipe ọba kò mu isánsa rẹ̀ bọ̀ wá ile.
14Nitoripe awa o sa kú, a o si dabi omi ti a tú silẹ ti a kò si le ṣajọ mọ; nitori bi Ọlọrun kò ti gbà ẹmi rẹ̀, o si ti ṣe ọna ki a má bà lé isánsa rẹ̀ kuro lọdọ rẹ̀.
15Njẹ nitorina li emi si ṣe wá isọ nkan yi fun oluwa mi ọba, bi o jẹpe awọn enia ti dẹrubà mi; iranṣẹbinrin rẹ si wi pe, Njẹ emi o sọ fun ọba; o le ri bẹ̃ pe ọba yio ṣe ifẹ iranṣẹbinrin rẹ̀ fun u.
16Nitoripe ọba o gbọ́, lati gbà iranṣẹbinrin rẹ̀ silẹ lọwọ ọkunrin na ti o nfẹ ke emi ati ọmọ mi pẹlu kuro ninu ilẹ ini Ọlọrun.
17Iranṣẹbinrin rẹ si wipe, Njẹ ọ̀rọ ọba oluwa mi yio si jasi itùnu: nitori bi angeli Ọlọrun bẹ̃ ni oluwa mi ọba lati mọ̀ rere ati buburu: Oluwa Ọlọrun rẹ yio si wà pẹlu rẹ.
18Ọba si dahùn, o si wi fun obinrin na pe, Máṣe fi nkan ti emi o bere lọwọ rẹ pamọ fun mi, emi bẹ̀ ọ. Obinrin na si wipe, Jẹ ki oluwa mi ọba ki o mã wi.
19Ọba si wipe, Ọwọ́ Joabu kò ha wà pẹlu rẹ ninu gbogbo eyi? obinrin na si dahun o si wipe, Bi ẹmi rẹ ti mbẹ lãye, oluwa mi ọba, kò si iyipada si ọwọ́ ọtun, tabi si ọwọ́ osi ninu gbogbo eyi ti oluwa mi ọba ti wi: nitoripe Joabu iranṣẹ rẹ, on li o rán mi, on li o si fi gbogbo ọ̀rọ wọnyi si iranṣẹbinrin rẹ li ẹnu.
20Lati mu iru ọ̀rọ wọnyi wá ni Joabu iranṣẹ rẹ si ṣe nkan yi: oluwa mi si gbọ́n, gẹgẹ bi ọgbọ́n angeli Ọlọrun, lati mọ̀ gbogbo nkan ti mbẹ li aiye.
21Ọba si wi fun Joabu pe, Wõ, emi o ṣe nkan yi: nitorina lọ, ki o si mu ọmọdekunrin na Absalomu pada wá.
22Joabu si wolẹ o doju rẹ̀ bolẹ, o si tẹriba fun u, o si sure fun ọba: Joabu si wipe, Loni ni iranṣẹ rẹ mọ̀ pe, emi ri ore-ọfẹ gbà li oju rẹ, oluwa mi, ọba, nitoripe ọba ṣe ifẹ iranṣẹ rẹ.
23Joabu si dide, o si lọ si Geṣuri, o si mu Absalomu wá si Jerusalemu.
24Ọba si wipe, Jẹ ki o yipada lọ si ile rẹ̀, má si ṣe jẹ ki o ri oju mi. Absalomu si yipada si ile rẹ̀, kò si ri oju ọba.
25Kò si si arẹwà kan ni gbogbo Israeli ti a ba yìn bi Absalomu: lati atẹlẹsẹ rẹ̀ titi de atari rẹ̀ kò si abùkun kan lara rẹ̀.
Ìjà Parí láàrin Absalomu ati Dafidi
26Nigbati o ba si rẹ́ irun ori rẹ̀ (nitoripe li ọdọdun li on ima rẹ́ ẹ nitoriti o wuwo fun u, on a si ma rẹ́ ẹ) on si wọ̀n irun ori rẹ̀, o si jasi igba ṣekeli ninu òṣuwọn ọba.
27A si bi ọmọkunrin mẹta fun Absalomu ati ọmọbinrin kan, orukọ rẹ̀ a si ma jẹ́ Tamari: on si jẹ obinrin ti o li ẹwà loju.
28Absalomu si joko li ọdun meji ni Jerusalemu kò si ri oju ọba.
29Absalomu si ranṣẹ si Joabu, lati rán a si ọba; ṣugbọn on kò fẹ wá sọdọ rẹ̀; o si ranṣẹ lẹ̃keji on kò si fẹ wá.
30O si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Wõ, oko Joabu gbè ti emi, o si ni ọkà nibẹ; ẹ lọ ki ẹ si tinabọ̀ ọ. Awọn iranṣẹ Absalomu si tinabọ oko na.
31Joabu si dide, o si tọ Absalomu wá ni ile, o si wi fun u pe, Ẽṣe ti awọn iranṣẹ rẹ fi tinabọ oko mi?
32Absalomu si da Joabu lohùn pe, Wõ, emi ranṣẹ si ọ, wipe, Wá nihinyi, emi o si rán ọ lọ sọdọ ọba, lati wi pe, Kili emi ti Geṣuri wá si? iba sàn fun mi bi o ṣepe emi wà nibẹ̀ sibẹ. Njẹ emi nfẹ ri oju ọba; bi o ba si ṣe pe ẹ̀ṣẹ mbẹ li ara mi, ki o pa mi.
33Joabu si tọ̀ ọba wá, o si rò fun u: o si ranṣẹ pe Absalomu, on si wá sọdọ ọba, o tẹriba fun u, o si doju rẹ̀ bolẹ niwaju ọba; ọba si fi ẹnu ko Absalomu li ẹnu.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Sam 14: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.