Ki ẹ kọ́ mọ̀ eyi pe, nigba ọjọ ikẹhin, awọn ẹlẹgan yio de pẹlu ẹgan wọn, nwọn o mã rin nipa ifẹ ara wọn, Nwọn o si mã wipe, Nibo ni ileri wíwa rẹ̀ gbé wà? lati igbati awọn baba ti sùn, ohun gbogbo nlọ bi nwọn ti wà rí lati ìgba ọjọ ìwa. Nitori eyi ni nwọn mọ̃mọ ṣe aifẹ̃mọ, pe nipa ọ̀rọ Ọlọrun li awọn ọrun ti wà lati ìgba atijọ, ati ti ilẹ yọri jade ninu omi, ti o si duro ninu omi: Nipa eyi ti omi bo aiye ti o wà nigbana, ti o si ṣegbe: Ṣugbọn awọn ọrun ati aiye, ti mbẹ nisisiyi, nipa ọ̀rọ kanna li a ti tojọ bi iṣura fun iná, a pa wọn mọ́ dè ọjọ idajọ ati iparun awọn alaiwa-bi-Ọlọrun. Ṣugbọn, olufẹ, ẹ máṣe gbagbe ohun kan yi, pe ọjọ kan lọdọ Oluwa bi ẹgbẹ̀run ọdún li o ri, ati ẹgbẹ̀run ọdún bi ọjọ kan. Oluwa kò fi ileri rẹ̀ jafara, bi awọn ẹlomiran ti ikà a si ijafara; ṣugbọn o nmu sũru fun nyin nitori kò fẹ ki ẹnikẹni ki o ṣegbé, bikoṣe ki gbogbo enia ki o wá si ironupiwada.
Kà II. Pet 3
Feti si II. Pet 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Pet 3:3-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò