Nitori ki iṣe bi ẹniti ntọ ìtan asan lẹhin ti a fi ọgbọ́n-kọgbọn là silẹ, li awa fi agbara ati wíwá Jesu Kristi Oluwa wa hàn nyin, ṣugbọn ẹlẹri ọlá nla rẹ̀ li awa iṣe. Nitoriti o gbà ọlá on ogo lati ọdọ Ọlọrun Baba, nigbati irú ohùn nì fọ̀ si i lati inu ogo nla na wá pe, Eyi li ayanfẹ Ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si jọjọ. Ohùn yi ti o ti ọrun wá li awa si gbọ́, nigbati awa mbẹ pẹlu rẹ̀ lori òke mimọ́ na. Awa si ni ọ̀rọ asọtẹlẹ ti o fẹsẹmulẹ jubẹ̃lọ; eyiti o yẹ ki ẹ kiyesi bi fitila ti ntàn ni ibi òkunkun, titi ilẹ yio fi mọ́, ti irawọ owurọ̀ yio si yọ li ọkàn nyin. Ki ẹ kọ́ mọ̀ eyi, pe kò si ọ̀kan ninu asọtẹlẹ inu iwe-mimọ́ ti o ni itumọ̀ ikọkọ. Nitori asọtẹlẹ kan kò ti ipa ifẹ enia wá ri; ṣugbọn awọn enia nsọrọ lati ọdọ Ọlọrun bi a ti ndari wọn lati ọwọ́ Ẹmí Mimọ́ wá.
Kà II. Pet 1
Feti si II. Pet 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Pet 1:16-21
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò