II. Pet 1:12-21

II. Pet 1:12-21 YBCV

Nitorina emi ó mã mura lati mã mu nkan wọnyi wá si iranti nyin nigbagbogbo bi ẹnyin tilẹ ti mọ̀ wọn, ti ẹsẹ nyin si mulẹ ninu otitọ ti ẹnyin ni. Emi si rò pe o yẹ, niwọn igbati emi ba mbẹ ninu agọ́ yi, lati mã fi iranti rú nyin soke; Bi emi ti mọ̀ pe, bibọ́ agọ́ mi yi silẹ kù si dẹdẹ, ani bi Oluwa wa Jesu Kristi ti fihàn mi. Emi o si mã ṣãpọn pẹlu, ki ẹnyin ki o le mã ranti nkan wọnyi nigbagbogbo lẹhin ikú mi. Nitori ki iṣe bi ẹniti ntọ ìtan asan lẹhin ti a fi ọgbọ́n-kọgbọn là silẹ, li awa fi agbara ati wíwá Jesu Kristi Oluwa wa hàn nyin, ṣugbọn ẹlẹri ọlá nla rẹ̀ li awa iṣe. Nitoriti o gbà ọlá on ogo lati ọdọ Ọlọrun Baba, nigbati irú ohùn nì fọ̀ si i lati inu ogo nla na wá pe, Eyi li ayanfẹ Ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si jọjọ. Ohùn yi ti o ti ọrun wá li awa si gbọ́, nigbati awa mbẹ pẹlu rẹ̀ lori òke mimọ́ na. Awa si ni ọ̀rọ asọtẹlẹ ti o fẹsẹmulẹ jubẹ̃lọ; eyiti o yẹ ki ẹ kiyesi bi fitila ti ntàn ni ibi òkunkun, titi ilẹ yio fi mọ́, ti irawọ owurọ̀ yio si yọ li ọkàn nyin. Ki ẹ kọ́ mọ̀ eyi, pe kò si ọ̀kan ninu asọtẹlẹ inu iwe-mimọ́ ti o ni itumọ̀ ikọkọ. Nitori asọtẹlẹ kan kò ti ipa ifẹ enia wá ri; ṣugbọn awọn enia nsọrọ lati ọdọ Ọlọrun bi a ti ndari wọn lati ọwọ́ Ẹmí Mimọ́ wá.