II. A. Ọba 7
7
1NIGBANA ni Eliṣa wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa: Bayi li Oluwa wi, Ni iwòyi ọla li a o ta oṣùwọn iyẹ̀fun kikuna kan ni ṣekeli kan ni ẹnu bode Samaria.
2Nigbana ni ijòye kan li ọwọ ẹniti ọba nfi ara tì dá enia Ọlọrun li ohùn, o si wipe, Kiyesi i, bi Oluwa tilẹ ṣí ferese li ọrun, nkan yi ha le ri bẹ̃? On si wipe, Kiyesi i, iwọ o fi oju rẹ ri i, ṣugbọn iwọ kì yio jẹ ninu rẹ̀.
Ogun Siria pada Sílé
3Adẹtẹ̀ mẹrin kan si wà ni atiwọ̀ bodè; nwọn si wi fun ara wọn pe, Ẽṣe ti awa fi joko nihinyi titi awa o fi kú?
4Bi awa ba wipe, Awa o wọ̀ ilu lọ, iyàn si mbẹ ni ilu, awa o si kú nibẹ: bi awa ba si joko jẹ nihinyi, awa o kú pẹlu. Njẹ nisisiyi ẹ wá, ẹ jẹ ki awa ki o ṣubu si ọwọ ogun awọn ara Siria: bi nwọn ba dá wa si, awa o yè: bi nwọn ba si pa wa, awa o kú na ni.
5Nwọn si dide li afẹ̀mọjumọ lati lọ si ibùdo awọn ara Siria: nigbati nwọn si de apa ti o kangun ibùdo Siria, kiyesi i, kò si ọkunrin kan nibẹ.
6Nitori ti Oluwa ṣe ki ogun awọn ara Siria ki o gbọ́ ariwo kẹkẹ́, ati ariwo ẹṣin, ariwo ogun nla: nwọn si wi fun ara wọn pe, Kiyesi i, ọba Israeli ti bẹ̀ ogun awọn ọba Hitti, ati awọn ọba Egipti si wa, lati wá bò wa mọlẹ.
7Nitorina ni nwọn dide, nwọn si salọ ni afẹ̀mọjumọ, nwọn si fi agọ wọn silẹ, ati ẹṣin wọn, ati kẹtẹkẹtẹ wọn, ani, ibùdo wọn gẹgẹ bi o ti wà, nwọn si salọ fun ẹmi wọn.
8Nigbati adẹtẹ̀ wọnyi de apa ikangun bùdo, nwọn wọ inu agọ kan lọ, nwọn jẹ, nwọn si mu, nwọn sì kó fadakà ati wura ati agbáda lati ibẹ lọ, nwọn si lọ, nwọn si pa a mọ́; nwọn si tún pada wá, nwọn si wọ̀ inu agọ miran lọ, nwọn si kó lati ibẹ lọ pẹlu, nwọn si lọ, nwọn si pa a mọ́.
9Nigbana ni nwọn wi fun ara wọn pe, Awa kò ṣe rere: oni yi, ọjọ ihinrere ni, awa si dakẹ: bi awa ba duro titi di afẹmọjumọ, iyà yio jẹ wa: njẹ nisisiyi ẹ wá, ẹ jẹ ki a si lọ isọ fun awọn ara ile ọba.
10Bẹ̃ni nwọn wá, nwọn si ke si awọn onibodè ilu; nwọn si wi fun wọn pe, Awa de bùdo awọn ara Siria, si kiyesi i, kò si ọkunrin kan nibẹ, bẹ̃ni kò si ohùn enia kan, bikòṣe ẹṣin ti a so, ati kẹtẹkẹtẹ ti a so, ati agọ bi nwọn ti wà.
11Ẹnikan si pè awọn onibodè; nwọn si sọ ninu ile ọba.
12Ọba si dide li oru, o si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Emi o fi hàn nyin nisisiyi eyiti awọn ara Siria ti ṣe si wa. Nwọn mọ̀ pe, ebi npa wa; nitorina nwọn jade lọ ni bùdo lati fi ara wọn pamọ́ ni igbẹ wipe, Nigbati nwọn ba jade ni ilu, awa o mu wọn lãyè, awa o si wọ̀ inu ilu lọ.
13Ọkan ninu awọn iranṣẹ rẹ̀ si dahùn o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki awa ki o mu marun ninu ẹṣin ti o kù, ninu awọn ti o kù ni ilu, kiyesi i, nwọn sa dabi gbogbo ọ̀pọlọpọ Israeli ti o kù ninu rẹ̀; kiyesi i, ani bi gbogbo ọ̀pọlọpọ enia Israeli ti a run, si jẹ ki a ranṣẹ lọ iwò.
14Nitorina nwọn mu ẹṣin kẹkẹ́ meji; ọba si ranṣẹ tọ̀ ogun awọn ara Siria lẹhin, wipe, Ẹ lọ iwò.
15Nwọn si tọ̀ wọn lẹhin de Jordani: si wò o, gbogbo ọ̀na kún fun agbáda ati ohun elò ti awọn ara Siria gbé sọnù ni iyára wọn. Awọn onṣẹ si pada, nwọn si sọ fun ọba.
16Awọn enia si jade lọ, nwọn si kó ibùdo awọn ara Siria. Bẹ̃ni a ntà oṣùwọn iyẹ̀fun kikunná kan ni ṣekeli kan, ati oṣuwọn barle meji ni ṣekeli kan, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa.
17Ọba si yàn ijòye na, lọwọ ẹniti o nfi ara tì, lati ṣe itọju ẹnu bodè: awọn enia si tẹ̀ ẹ mọlẹ ni bodè, o si kú, bi enia Ọlọrun na ti wi, ẹniti o sọ̀rọ nigbati ọba sọ̀kalẹ tọ̀ ọ wá.
18O si ṣe, bi enia Ọlọrun na ti sọ fun ọba, wipe, Oṣùwọn barle meji fun ṣekeli kan, ati òṣuwọn iyẹfun kikunná kan, fun ṣekeli kan, yio wà ni iwòyi ọla ni ẹnu bodè Samaria:
19Ijòye na si da enia Ọlọrun na li ohùn, o si wipe, Kiyesi i, nisisiyi, bi Oluwa tilẹ ṣe ferese li ọrun, iru nkan yi ha le ri bẹ̃? On si wipe, Kiyesi i, iwọ o fi oju rẹ ri i, ṣugbọn iwọ kì yio jẹ ninu rẹ̀.
20Bẹ̃li o si ri fun u: nitori awọn enia tẹ̀ ẹ mọlẹ ni ẹnu bodè, o si kú.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. A. Ọba 7: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.