II. A. Ọba 6:1-7

II. A. Ọba 6:1-7 YBCV

AWỌN ọmọ awọn woli wi fun Eliṣa pe, Sa wò o na, ibiti awa gbe njoko niwaju rẹ, o há jù fun wa. Jẹ ki awa ki o lọ, awa bẹ̀ ọ, si Jordani, ki olukulùku wa ki o mu iti igi kọ̃kan wá, si jẹ ki awa ki o ṣe ibikan, ti awa o ma gbe. On si dahùn wipe, Ẹ mã lọ. Ẹnikan si wipe, Ki o wu ọ, emi bẹ̀ ọ, lati ba awọn iranṣẹ rẹ lọ. On si dahùn pe, Emi o lọ. Bẹ̃li o ba wọn lọ. Nigbati nwọn si de Jordani, nwọn ké igi. O si ṣe, bi ẹnikan ti nké iti-igi, ãke yọ sinu omi: o si kigbe, o si wipe, Yẽ! oluwa mi, a tọrọ rẹ̀ ni. Enia Ọlọrun si wipe, Nibo li o bọ́ si? O si fi ibẹ hàn a. On si ké igi kan, o si sọ́ ọ sinu rẹ̀; irin na si fó soke. Nitorina o wipe, Mu u. On si nà ọwọ rẹ̀, o si mu u.