NJẸ Naamani, olori-ogun ọba Siria, jẹ enia nla niwaju oluwa rẹ̀, ati ọlọla, nitori nipa rẹ̀ ni Oluwa ti fi iṣẹgun fun Siria: on si jẹ alagbara akọni ọkunrin ṣugbọn adẹtẹ̀ ni.
Awọn ara Siria si ti jade lọ ni ẹgbẹ́-ẹgbẹ́, nwọn si ti mu ọmọbinrin kekere kan ni igbèkun lati ilẹ Israeli wá; on si duro niwaju obinrin Naamani.
On si wi fun iya rẹ̀ pe, oluwa mi iba wà niwaju woli ti mbẹ ni Samaria! nitõtọ on iba wò o sàn kuro ninu ẹ̀tẹ rẹ̀.
On si wọle, o si sọ fun oluwa rẹ̀ pe, Bayi bayi li ọmọdebinrin ti o ti ilẹ Israeli wá wi.
Ọba Siria si wipe, Wá na, lọ, emi o si fi iwe ranṣẹ si ọba Israeli. On si jade lọ, o si mu talenti fàdakà mẹwa lọwọ, ati ẹgbãta iwọ̀n wurà, ati ipãrọ aṣọ mẹwa.
On si mu iwe na tọ̀ ọba Israeli wá, wipe, Njẹ nisisiyi nigbati iwe yi ba de ọdọ rẹ, kiyesi i, emi rán Naamani iranṣẹ mi si ọ, ki iwọ ki o le wò o sàn kuro ninu ẹ̀tẹ rẹ̀.
O si ṣe, nigbati ọba Israeli kà iwe na tan, o si fà aṣọ rẹ̀ ya, o si wipe, Emi ha iṣe Ọlọrun, lati pa ati lati sọ di ãyè, ti eleyi fi ranṣẹ si mi lati ṣe awòtan enia kan kuro ninu ẹ̀tẹ rẹ̀? nitorina, ẹ rò o wò, mo bẹ̀ nyin, ki ẹ si wò o bi on ti nwá mi ni ijà.
O si ṣe, nigbati Eliṣa enia Ọlọrun gbọ́ pe, ọba Israeli fà aṣọ rẹ̀ ya, o si ranṣẹ si ọba wipe, Ẽṣe ti iwọ fi fà aṣọ rẹ ya? jẹ ki o tọ̀ mi wá nisisiyi, on o si mọ̀ pe, woli kan mbẹ ni Israeli.
Bẹ̃ni Naamani de pẹlu awọn ẹṣin rẹ̀ ati pẹlu kẹkẹ́ rẹ̀, o si duro li ẹnu-ọ̀na ile Eliṣa.
Eliṣa si ràn iranṣẹ kan si i wipe, Lọ, ki o si wẹ̀ ni Jordani nigba meje, ẹran-ara rẹ yio si tun bọ̀ sipò fun ọ, iwọ o si mọ́.
Ṣugbọn Naamani binu, o si pada lọ, o si wipe, Kiyesi, i, mo rò ninu mi pe, dajudaju on o jade tọ̀ mi wá, yio si duro, yio si kepè orukọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀, yio si fi ọwọ rẹ̀ pa ibẹ̀ na, yio si ṣe awòtan ẹ̀tẹ na.
Abana ati Farpari, awọn odò Damasku kò ha dara jù gbogbo awọn omi Israeli lọ? emi kì iwẹ̀ ninu wọn ki emi si mọ́? Bẹ̃li o yipada, o si jade lọ ni irúnu.
Awọn iranṣẹ rẹ̀ si sunmọ ọ, nwọn si ba a sọ̀rọ, nwọn si wipe, Baba mi, woli iba wi fun ọ pe, ki o ṣe ohun nla kan, iwọ kì ba ti ṣe e bi? melomelo, nigbati o wi fun ọ pe, Wẹ̀, ki o si mọ́?
Nigbana ni o sọ̀kalẹ, o si tẹ̀ ara rẹ̀ bọ inu Jordani nigba meje, gẹgẹ bi ọ̀rọ enia Ọlọrun: ẹran-ara rẹ̀ si tún pada bọ̀ gẹgẹ bi ẹran-ara ọmọ kekere, on si mọ́.
O si pada tọ̀ enia Ọlọrun na lọ, on, ati gbogbo ẹgbẹ́ rẹ̀, nwọn si wá, nwọn duro niwaju rẹ̀: on si wipe, wõ, nisisiyi ni mo to mọ̀ pe, Kò si Ọlọrun ni gbogbo aiye, bikòṣe ni Israeli: njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, gbà ẹbun lọwọ iranṣẹ rẹ.