LI ọdun kẹtadilogun Peka ọmọ Remaliah, Ahasi ọmọ Jotamu ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba. Ẹni ogún ọdun ni Ahasi nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹrindilogun ni Jerusalemu, kò si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa Ọlọrun rẹ̀, gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ̀. Ṣugbọn o rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, nitõtọ, o si mu ki ọmọ rẹ̀ ki o kọja lãrin iná pẹlu, gẹgẹ bi iṣe irira awọn keferi, ti Oluwa le jade niwaju awọn ọmọ Israeli. O si rubọ, o si sun turari ni ibi giga wọnni, ati lori awọn òke kekeke, ati labẹ gbogbo igi tutu.
Kà II. A. Ọba 16
Feti si II. A. Ọba 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. A. Ọba 16:1-4
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò