II. Kor 9

9
Ọrẹ fún Àwọn Onigbagbọ
1NITORI nipa ti ipinfunni fun awọn enia mimọ́, kò ni pe mo nkọwe si nyin ju bẹ̃ lọ.
2Nitori mo mọ̀ imura-tẹlẹ nyin, eyiti mo fi yangàn fun awọn ara Makedonia nitori nyin, pe, Akaia ti mura tan niwọn ọdún kan ti o kọja; itara nyin si ti rú ọ̀pọlọpọ soke.
3Ṣugbọn mo ti rán awọn arakunrin, ki iṣogo wa nitori nyin ki o máṣe jasi asan niti ọ̀ran yi; pe gẹgẹ bi mo ti wi, ki ẹnyin ki o le mura tẹlẹ:
4Bi awọn ninu ará Makedonia ba bá mi wá, ti nwọn si bá nyin li aimura tẹlẹ, ki oju ki o máṣe tì wa (laiwipe ẹnyin,) niti igbẹkẹle yi.
5Nitorina ni mo ṣe rò pe o yẹ lati gbà awọn arakunrin niyanju, ki nwọn ki o ṣaju tọ̀ nyin wá, ki nwọn ki o si mura ẹ̀bun nyin silẹ, ti ẹ ti ṣe ileri tẹlẹ ki a le ṣe eyi na silẹ, ki o le jasi bi ohun ẹ̀bun, ki o má si ṣe dabi ti ojukòkoro.
6Ṣugbọn eyi ni mo wipe, Ẹniti o ba funrugbin kiun, kiun ni yio ká; ẹniti o ba si funrugbin, pupọ, pupọ ni yio ká.
7Ki olululuku enia ki o ṣe gẹgẹ bi o ti pinnu li ọkàn rẹ̀; kì iṣe àfẹ̀kùnṣe, tabi ti alaigbọdọ má ṣe: nitori Ọlọrun fẹ oninudidun ọlọrẹ.
8Ọlọrun si le mu ki gbogbo ore-ọfẹ ma bisi i fun nyin; ki ẹnyin, ti o ni anito ohun gbogbo nigbagbogbo, le mã pọ̀ si i ni iṣẹ́ rere gbogbo:
9(Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, O ti fọnka; o ti fifun awọn talakà: ododo rẹ̀ duro lailai.
10Njẹ ẹniti nfi irugbin fun afunrugbin, ati akara fun onjẹ, yio fi irugbin fun nyin, yio si sọ ọ di pipọ fun irugbin, yio si mu eso ododo nyin bi si i.)
11Ẹnyin ti a ti sọ di ọlọrọ̀ ninu ohun gbogbo, fun ilawọ gbogbo ti nṣiṣẹ ọpẹ si Ọlọrun nipa wa.
12Nitori iṣẹ-iranṣẹ ìsin yi kò fi kun iwọn aini awọn enia mimọ́ nikan, ṣugbọn o tubọ pọ si i nipa ọ̀pọlọpọ ọpẹ́ si Ọlọrun,
13Lẹhin ti nwọn fi iṣẹ-isin yi dan nyin wo, nwọn yin Ọlọrun li ogo fun itẹriba ijẹwọ́ nyin si ihinrere Kristi, ati fun ilàwọ ìdawó nyin fun wọn ati fun gbogbo enia;
14Nigbati awọn tikarawọn pẹlu ẹ̀bẹ nitori nyin nṣafẹri nyin nitori ọpọ ore-ọfẹ Ọlọrun ti mbẹ ninu nyin.
15Ọpẹ́ ni fun Ọlọrun nitori alailesọ ẹ̀bun rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. Kor 9: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀