II. Kor 6
6
1NJẸ bi alabaṣiṣẹpọ pẹlu rẹ̀, awa mbẹ̀ nyin ki ẹ máṣe gbà ore-ọfẹ Ọlọrun lasan.
2(Nitori o wipe, emi ti gbohùn rẹ li akokò itẹwọgbà, ati li ọjọ igbala ni mo si ti ràn ọ lọwọ: kiyesi i, nisisiyi ni akokò itẹwọgbà; kiyesi i, nisisiyi ni ọjọ igbala.)
3A kò si ṣe ohun ikọsẹ li ohunkohun, ki iṣẹ-iranṣẹ ki o máṣe di isọrọ buburu si.
4Ṣugbọn li ohun gbogbo awa nfi ara wa han bi awọn iranṣẹ Ọlọrun ninu ọ̀pọlọpọ sũru, ninu ipọnju, ninu aini, ninu wahalà,
5Nipa ìnà, ninu tubu, nipa ìrúkerudo, nipa ìṣẹ́, ninu iṣọra, ninu igbawẹ;
6Nipa ìwa mimọ́, nipa ìmọ, nipa ipamọra, nipa iṣeun, nipa Ẹmi Mimọ́, nipa ifẹ aiṣẹtan,
7Nipa ọ̀rọ otitọ, nipa agbara Ọlọrun, nipa ihamọra ododo li apa ọtún ati li apa òsi,
8Nipa ọlá ati ẹ̀gan, nipa ìhin buburu ati ìhin rere: bi ẹlẹtan, ṣugbọn a jasi olõtọ;
9Bi ẹniti a kò mọ̀, ṣugbọn a mọ̀ wa dajudaju; bi ẹniti nkú lọ, si kiyesi i, awa wà lãye; bi ẹniti a ńnà, a kò si pa wa;
10Bi ẹniti o kún fun ibinujẹ, ṣugbọn awa nyọ̀ nigbagbogbo; bi talakà, ṣugbọn awa nsọ ọ̀pọlọpọ di ọlọrọ̀; bi ẹniti kò ni nkan, ṣugbọn awa ni ohun gbogbo.
11Ẹnyin ara Korinti, a ti bá nyin sọ otitọ ọ̀rọ, ọkàn wa ṣipayá sí nyin.
12A kò ni nyin lara nitori wa, ṣugbọn a ńni nyin lara nitori ifẹ-ọkàn ẹnyin tikaranyin.
13Njẹ fun ẹsan iru kanna (emi nsọ bi ẹnipe fun awọn ọmọ mi,) ki ẹnyin di kikún pẹlu.
Ilé Ọlọrun Alààyè
14Ẹ máṣe fi aidọgba dàpọ pẹlu awọn alaigbagbọ́: nitori ìdapọ kili ododo ni pẹlu aiṣododo? ìdapọ kini imọlẹ si ni pẹlu òkunkun?
15Irẹpọ̀ kini Kristi si ni pẹlu Beliali? tabi ipin wo li ẹniti o gbagbọ́ ni pẹlu alaigbàgbọ?
16Irẹpọ̀ kini tẹmpili Ọlọrun si ni pẹlu oriṣa? nitori ẹnyin ni tẹmpili Ọlọrun alãye; gẹgẹ bi Ọlọrun ti wipe, Emi ó gbé inu wọn, emi o si mã rìn ninu wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, nwọn o si jẹ enia mi.
17Nitorina ẹ jade kuro larin wọn, ki ẹ si yà ara nyin si ọ̀tọ, li Oluwa wi, ki ẹ máṣe fi ọwọ́ kàn ohun aimọ́; emi o si gbà nyin.
18Emi o si jẹ Baba fun nyin, ẹnyin o si jẹ ọmọkunrin mi ati ọmọbinrin mi, li Oluwa Olodumare wi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Kor 6: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.