II. Kor 5:6-21

II. Kor 5:6-21 YBCV

Nitorina awa ni igboiya nigbagbogbo, awa si mọ̀ pe, nigbati awa mbẹ ni ile ninu ara, awa kò si lọdọ Oluwa: (Nitoripe nipa igbagbọ́ li awa nrìn, kì iṣe nipa riri:) Mo ni, awa ni igboiya, awa si nfẹ ki a kuku ti inu ara kuro, ki a si le wà ni ile lọdọ Oluwa. Nitorina awa ndù u, pe bi awa ba wà ni ile tabi bi a kò si, ki awa ki o le jẹ ẹni itẹwọgbà lọdọ rẹ̀. Nitoripe gbogbo wa kò le ṣaima fi ara hàn niwaju itẹ́ idajọ Kristi; ki olukuluku ki o le gbà nkan wọnni ti o ṣe ninu ara, gẹgẹ bi eyi ti o ti ṣe, ibã ṣe rere ibã ṣe buburu. Nitorina bi awa ti mọ̀ ẹ̀ru Oluwa, awa nyi enia li ọkàn pada; ṣugbọn a nfi wa hàn fun Ọlọrun; mo si gbagbọ́ pe, a si fi wa hàn li ọkàn nyin pẹlu. Nitori awa kò si ni tún mã yìn ara wa si nyin mọ́, ṣugbọn awa fi àye fun nyin lati mã ṣogo nitori wa, ki ẹ le ni ohun ti ẹ ó fi da wọn lohùn, awọn ti nṣogo lode ara kì isi iṣe li ọkàn. Nitorina bi ori wa ba bajẹ, fun Ọlọrun ni: tabi bi iye wa ba walẹ̀, fun nyin ni. Nitori ifẹ Kristi nrọ̀ wa; nitori awa rò bayi, pe bi ẹnikan ba ti kú fun gbogbo enia, njẹ gbogbo wọn li o ti kú: O si ti kú fun gbogbo wọn, pe ki awọn ti o wà lãye ki o má si ṣe wà lãye fun ara wọn mọ́, bikoṣe fun ẹniti o kú nitori wọn, ti o si ti jinde. Nitorina lati isisiyi lọ awa kò mọ̀ ẹnikan nipa ti ara mọ́; bi awa tilẹ ti mọ̀ Kristi nipa ti ara, ṣugbọn nisisiyi awa kò mọ̀ ọ bẹ̃ mọ́. Nitorina bi ẹnikẹni ba wà ninu Kristi, o di ẹda titun: ohun atijọ ti kọja lọ; kiyesi i, nwọn si di titun. Ohun gbogbo si ti ọdọ Ọlọrun wá, ẹniti o si ti ipasẹ Jesu Kristi ba wa laja sọdọ ara rẹ̀, ti o si ti fi iṣẹ-iranṣẹ ìlaja fun wa; Eyini ni pe, Ọlọrun wà nínu Kristi, o mba araiye làja sọdọ ara rẹ̀, kò si kà irekọja wọn si wọn lọrùn; o si ti fi ọ̀rọ ìlaja le wa lọwọ. Nitorina awa ni ikọ̀ fun Kristi, bi ẹnipe Ọlọrun nti ọdọ wa ṣipẹ fun nyin: awa mbẹ̀ nyin nipò Kristi, ẹ ba Ọlọrun làja. Nitori o ti fi i ṣe ẹ̀ṣẹ nitori wa, ẹniti kò mọ̀ ẹ̀ṣẹkẹṣẹ rí; ki awa le di ododo Ọlọrun ninu rẹ̀.

Verse Images for II. Kor 5:6-21

II. Kor 5:6-21 - Nitorina awa ni igboiya nigbagbogbo, awa si mọ̀ pe, nigbati awa mbẹ ni ile ninu ara, awa kò si lọdọ Oluwa:
(Nitoripe nipa igbagbọ́ li awa nrìn, kì iṣe nipa riri:)
Mo ni, awa ni igboiya, awa si nfẹ ki a kuku ti inu ara kuro, ki a si le wà ni ile lọdọ Oluwa.
Nitorina awa ndù u, pe bi awa ba wà ni ile tabi bi a kò si, ki awa ki o le jẹ ẹni itẹwọgbà lọdọ rẹ̀.
Nitoripe gbogbo wa kò le ṣaima fi ara hàn niwaju itẹ́ idajọ Kristi; ki olukuluku ki o le gbà nkan wọnni ti o ṣe ninu ara, gẹgẹ bi eyi ti o ti ṣe, ibã ṣe rere ibã ṣe buburu.

Nitorina bi awa ti mọ̀ ẹ̀ru Oluwa, awa nyi enia li ọkàn pada; ṣugbọn a nfi wa hàn fun Ọlọrun; mo si gbagbọ́ pe, a si fi wa hàn li ọkàn nyin pẹlu.
Nitori awa kò si ni tún mã yìn ara wa si nyin mọ́, ṣugbọn awa fi àye fun nyin lati mã ṣogo nitori wa, ki ẹ le ni ohun ti ẹ ó fi da wọn lohùn, awọn ti nṣogo lode ara kì isi iṣe li ọkàn.
Nitorina bi ori wa ba bajẹ, fun Ọlọrun ni: tabi bi iye wa ba walẹ̀, fun nyin ni.
Nitori ifẹ Kristi nrọ̀ wa; nitori awa rò bayi, pe bi ẹnikan ba ti kú fun gbogbo enia, njẹ gbogbo wọn li o ti kú:
O si ti kú fun gbogbo wọn, pe ki awọn ti o wà lãye ki o má si ṣe wà lãye fun ara wọn mọ́, bikoṣe fun ẹniti o kú nitori wọn, ti o si ti jinde.
Nitorina lati isisiyi lọ awa kò mọ̀ ẹnikan nipa ti ara mọ́; bi awa tilẹ ti mọ̀ Kristi nipa ti ara, ṣugbọn nisisiyi awa kò mọ̀ ọ bẹ̃ mọ́.
Nitorina bi ẹnikẹni ba wà ninu Kristi, o di ẹda titun: ohun atijọ ti kọja lọ; kiyesi i, nwọn si di titun.
Ohun gbogbo si ti ọdọ Ọlọrun wá, ẹniti o si ti ipasẹ Jesu Kristi ba wa laja sọdọ ara rẹ̀, ti o si ti fi iṣẹ-iranṣẹ ìlaja fun wa;
Eyini ni pe, Ọlọrun wà nínu Kristi, o mba araiye làja sọdọ ara rẹ̀, kò si kà irekọja wọn si wọn lọrùn; o si ti fi ọ̀rọ ìlaja le wa lọwọ.
Nitorina awa ni ikọ̀ fun Kristi, bi ẹnipe Ọlọrun nti ọdọ wa ṣipẹ fun nyin: awa mbẹ̀ nyin nipò Kristi, ẹ ba Ọlọrun làja.
Nitori o ti fi i ṣe ẹ̀ṣẹ nitori wa, ẹniti kò mọ̀ ẹ̀ṣẹkẹṣẹ rí; ki awa le di ododo Ọlọrun ninu rẹ̀.II. Kor 5:6-21 - Nitorina awa ni igboiya nigbagbogbo, awa si mọ̀ pe, nigbati awa mbẹ ni ile ninu ara, awa kò si lọdọ Oluwa:

Nitori o ti fi i ṣe ẹ̀ṣẹ nitori wa, ẹniti kò mọ̀ ẹ̀ṣẹkẹṣẹ rí; ki awa le di ododo Ọlọrun ninu rẹ̀.