II. Kor 4:7-18

II. Kor 4:7-18 YBCV

Ṣugbọn awa ni iṣura yi ninu ohun èlo amọ̀, ki ọlá nla agbara na ki o le ṣe ti Ọlọrun, ki o má ti ọdọ wa wá. A npọn wa loju niha gbogbo, ṣugbọn ara kò ní wa: a ndãmú wa, ṣugbọn a kò sọ ireti nù. A nṣe inunibini si wa, ṣugbọn a kò kọ̀ wa silẹ; a nrẹ̀ wa silẹ, ṣugbọn a kò si pa wa run; Nigbagbogbo awa nru ikú Jesu Oluwa kiri li ara wa, ki a le fi ìye Jesu hàn pẹlu li ara wa. Nitoripe nigbagbogbo li a nfi awa ti o wà lãyè fun ikú nitori Jesu, ki a le fi ìye Jesu hàn ninu ara kikú wa pẹlu. Bẹ̃ni ikú nṣiṣẹ ninu wa, ṣugbọn ìye ninu nyin. Awa li ẹmí igbagbọ́ kanna, gẹgẹ bi a ti kọ́ ọ pe, emi gbagbọ́, nitorina li emi ṣe sọ: awa pẹlu gbagbọ́, nitorina li awa si ṣe nsọ; Awa mọ̀ pe, ẹniti o jí Jesu Oluwa dide yio si jí wa dide pẹlu nipa Jesu, yio si mu wa wá iwaju rẹ̀ pẹlu nyin. Nitoripe tinyin li ohun gbogbo, ki ọpọ̀ ore-ọfẹ nipa awọn pipọ le mu ki ọpẹ di pipọ fun ogo Ọlọrun. Nitori eyi ni ãrẹ̀ kò ṣe mu wa; ṣugbọn bi ọkunrin ti ode wa ba nparun, sibẹ ọkunrin ti inu wa ndi titun li ojojumọ́. Nitori ipọnju wa ti o fẹrẹ, ti iṣe fun iṣẹ́ju kan, o nṣiṣẹ ogo ainipẹkun ti o pọ̀ rekọja fun wa. Niwọn bi a kò ti wò ohun ti a nri, bikoṣe ohun ti a kò ri: nitori ohun ti a nri ni ti igba isisiyi; ṣugbọn ohun ti a kò ri ni ti aiyeraiye.

Verse Images for II. Kor 4:7-18

II. Kor 4:7-18 - Ṣugbọn awa ni iṣura yi ninu ohun èlo amọ̀, ki ọlá nla agbara na ki o le ṣe ti Ọlọrun, ki o má ti ọdọ wa wá.
A npọn wa loju niha gbogbo, ṣugbọn ara kò ní wa: a ndãmú wa, ṣugbọn a kò sọ ireti nù.
A nṣe inunibini si wa, ṣugbọn a kò kọ̀ wa silẹ; a nrẹ̀ wa silẹ, ṣugbọn a kò si pa wa run;
Nigbagbogbo awa nru ikú Jesu Oluwa kiri li ara wa, ki a le fi ìye Jesu hàn pẹlu li ara wa.
Nitoripe nigbagbogbo li a nfi awa ti o wà lãyè fun ikú nitori Jesu, ki a le fi ìye Jesu hàn ninu ara kikú wa pẹlu.
Bẹ̃ni ikú nṣiṣẹ ninu wa, ṣugbọn ìye ninu nyin.
Awa li ẹmí igbagbọ́ kanna, gẹgẹ bi a ti kọ́ ọ pe, emi gbagbọ́, nitorina li emi ṣe sọ: awa pẹlu gbagbọ́, nitorina li awa si ṣe nsọ;
Awa mọ̀ pe, ẹniti o jí Jesu Oluwa dide yio si jí wa dide pẹlu nipa Jesu, yio si mu wa wá iwaju rẹ̀ pẹlu nyin.
Nitoripe tinyin li ohun gbogbo, ki ọpọ̀ ore-ọfẹ nipa awọn pipọ le mu ki ọpẹ di pipọ fun ogo Ọlọrun.

Nitori eyi ni ãrẹ̀ kò ṣe mu wa; ṣugbọn bi ọkunrin ti ode wa ba nparun, sibẹ ọkunrin ti inu wa ndi titun li ojojumọ́.
Nitori ipọnju wa ti o fẹrẹ, ti iṣe fun iṣẹ́ju kan, o nṣiṣẹ ogo ainipẹkun ti o pọ̀ rekọja fun wa.
Niwọn bi a kò ti wò ohun ti a nri, bikoṣe ohun ti a kò ri: nitori ohun ti a nri ni ti igba isisiyi; ṣugbọn ohun ti a kò ri ni ti aiyeraiye.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú II. Kor 4:7-18