II. Kro 33

33
Manase, Ọba Juda
(II. A. Ọba 21:1-9)
1ẸNI ọdun mejila ni Manasse, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun marundilọgọta ni Jerusalemu:
2Ṣugbọn o ṣe buburu li oju Oluwa, bi irira awọn orilẹ-ède, ti Oluwa le jade niwaju awọn ọmọ Israeli.
3Nitori ti o tun kọ́ ibi giga wọnni ti Hesekiah baba rẹ̀, ti wó lulẹ, o si gbé pẹpẹ wọnni soke fun Baalimu, o si ṣe ere oriṣa, o si mbọ gbogbo ogun ọrun, o si nsìn wọn.
4O tẹ́ pẹpẹ pẹlu ni ile Oluwa, niti eyiti Oluwa ti sọ pe; Ni Jerusalemu li orukọ mi yio wà lailai.
5O si tẹ́ pẹpẹ fun gbogbo ogun ọrun li àgbala mejeji ile Oluwa.
6O si mu ki awọn ọmọ rẹ̀ ki o kọja lãrin iná àfonifoji ọmọ Hinnomu: ati pẹlu o nṣe akiyesi afọṣẹ, o si nlò alupayida, o si nṣe ajẹ́, o si mba okú lò, ati pẹlu oṣó: o ṣe buburu pupọ̀ li oju Oluwa lati mu u binu.
7O si gbé ere gbigbẹ kalẹ, ere ti o ti yá sinu ile Ọlọrun, niti eyiti Ọlọrun ti sọ fun Dafidi ati Solomoni, ọmọ rẹ̀, pe, Ninu ile yi, ati ni Jerusalemu ti emi ti yàn ninu gbogbo ẹ̀ya Israeli, li emi o fi orukọ mi si lailai:
8Bẹ̃li emi kì yio ṣi ẹsẹ Israeli mọ kuro ni ilẹ na ti emi ti yàn fun awọn baba nyin; kiki bi nwọn ba ṣe akiyesi lati ṣe gbogbo eyiti emi ti pa li aṣẹ fun wọn, gẹgẹ bi gbogbo ofin ati aṣẹ ati ilana lati ọwọ Mose wá.
9Bẹ̃ni Manasse mu ki Judah ati awọn ti ngbe Jerusalemu ki o yapa, ati lati ṣe buburu jù awọn orilẹ-ède lọ, awọn ẹniti Oluwa ti parun niwaju awọn ọmọ Israeli.
Manase Ronupiwada
10Oluwa si ba Manasse wi ati awọn enia rẹ̀; ṣugbọn nwọn kò kiyesi i.
11Nitorina li Oluwa mu awọn balogun ogun Assiria wá ba wọn, ti nwọn fi ìwọ mu Manasse, nwọn si de e li ẹ̀wọn, nwọn mu u lọ si Babeli.
12Nigbati o si wà ninu wahala, o bẹ̀ Oluwa Ọlọrun rẹ̀, o si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ gidigidi niwaju Ọlọrun awọn baba rẹ̀,
13O si gbadura si i: Ọlọrun si gbọ́ ẹ̀bẹ rẹ̀, o si tun mu u pada wá si Jerusalemu sinu ijọba rẹ̀. Nigbana ni Manasse mọ̀ pe: Oluwa, On li Ọlọrun.
14Njẹ lẹhin eyi, o mọ odi kan lẹhin ilu Dafidi, niha ìwọ-õrun Gihoni, li àfonifoji, ani li atiwọ ẹnu-bode ẹja, o si yi Ofeli ka, o si mọ ọ ga soke gidigidi, o si fi balogun sinu gbogbo ilú olodi Juda wọnni.
15O si kó awọn àjeji ọlọrun ati ere kuro ni ile Oluwa, ati gbogbo pẹpẹ ti o ti tẹ́ lori òke ile Oluwa ati ni Jerusalemu, o si kó wọn danu kuro ni ilu.
16O si tun pẹpẹ Oluwa ṣe, o si rú ẹbọ alafia ati ẹbọ ọpẹ lori rẹ̀, o si paṣẹ fun Juda lati ma sìn Oluwa Ọlọrun Israeli.
17Sibẹ awọn enia nṣe irubọ ni ibi giga wọnni, kiki si Oluwa, Ọlọrun wọn nikan ni.
Ìgbẹ̀yìn Ìjọba Manase
(II. A. Ọba 21:17-18)
18Ati iyokù iṣe Manasse, ati adura rẹ̀ si Ọlọrun rẹ̀, ati ọ̀rọ awọn ariran ti o ba a sọ̀rọ li orukọ Oluwa Ọlọrun Israeli, kiye si i, o wà ninu iwe ọba Israeli.
19Adura rẹ̀ na pẹlu, bi Ọlọrun ti gbọ́ ẹ̀bẹ rẹ̀, ati gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ati irekọja rẹ̀ ati ibi ti o gbe kọ́ ibi giga wọnni ti o si gbé ere-oriṣa kalẹ, ati awọn ere yiyá, ki a to rẹ̀ ẹ silẹ, kiye si i, a kọ wọn sinu iwe itan Hosai.
20Manasse si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sìn i si ile on tikalarẹ̀: Amoni, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.
Amoni, Ọba Juda
(II. A. Ọba 21:19-26)
21Ẹni ọdun mejilelogun ni Amoni, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun meji ni Jerusalemu.
22O si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa, bi Manasse, baba rẹ̀ ti ṣe, nitori Amoni rubọ si gbogbo awọn ere yiyá, ti Manasse baba rẹ̀ ti ṣe, o si sìn wọn:
23Kò si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ niwaju Oluwa bi Manasse, baba rẹ̀, ti rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ; ṣugbọn Amoni dẹṣẹ pupọpupọ.
24Awọn iranṣẹ rẹ̀ si di rikiṣi si i, nwọn si pa a ni ile rẹ̀.
25Awọn enia ilẹ na si pa gbogbo awọn ti o ti di rikiṣi si Amoni, ọba; awọn enia ilẹ na si fi Josiah, ọmọ rẹ̀, jọba ni ipò rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. Kro 33: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀