O si wipe, Oluwa, Ọlọrun awọn baba wa, iwọ kọ́ ha ni Ọlọrun li ọrun? Iwọ kọ́ ha nṣakoso lori gbogbo ijọba awọn orilẹ-ède? lọwọ rẹ ki agbara ati ipá ha wà, ti ẹnikan kò si, ti o le kò ọ loju?
Iwọ ha kọ́ Ọlọrun wa, ti o ti le awọn ara ilẹ yi jade niwaju Israeli enia rẹ, ti o si fi fun iru-ọmọ Abrahamu, ọrẹ rẹ lailai?
Nwọn si ngbe inu rẹ̀, nwọn si kọ́ ibi-mimọ́ fun ọ ninu rẹ̀ fun orukọ rẹ, pe,
Bi ibi ba de si wa, bi idà, ijiya tabi àjakalẹ-àrun, tabi ìyan, bi awa ba duro niwaju ile yi, ati niwaju rẹ, (nitori orukọ rẹ wà ni ile yi): bi a ba ke pè ọ ninu wàhala wa, nigbana ni iwọ o gbọ́, iwọ o si ṣe iranlọwọ.
Njẹ nisisiyi, kiyesi i, awọn ọmọ Ammoni ati Moabu, ati awọn ara òke Seiri, ti iwọ kò jẹ ki Israeli gbogun si nigbati nwọn jade ti ilẹ Egipti wá, ṣugbọn nwọn yipada kuro lọdọ wọn, nwọn kò si run wọn;
Si kiyesi i, bi nwọn ti san a pada fun wa; lati wá le wa jade kuro ninu ini rẹ, ti iwọ ti fi fun wa lati ni.
Ọlọrun wa! Iwọ kì o ha da wọn lẹjọ? nitori awa kò li agbara niwaju ọ̀pọlọpọ nla yi, ti mbọ̀ wá ba wa; awa kò si mọ̀ eyi ti awa o ṣe: ṣugbọn oju wa mbẹ lara rẹ.