II. Kro 19

19
Wolii Kan Bá Jehoṣafati Wí
1JEHOṢAFATI, ọba Juda, si pada lọ si ile rẹ̀ ni Jerusalemu li alafia.
2Jehu, ọmọ Hanani, ariran, si jade lọ ipade rẹ̀, o si wi fun Jehoṣafati pe, iwọ o ha ma ràn enia buburu lọwọ, iwọ o si fẹran awọn ti o korira Oluwa? njẹ nitori eyi ni ibinu ṣe de si ọ lati ọdọ Oluwa.
3Ṣugbọn a ri ohun rere ninu rẹ, pe, nitori ti iwọ ti mu awọn ere-oriṣa kuro ni ilẹ na, ti o si mura ọkàn rẹ lati wá Ọlọrun.
Jehoṣafati Ṣe Àtúnṣe
4Jehoṣafati si ngbe Jerusalemu: o nlọ, o mbọ̀ lãrin awọn enia lati Beerṣeba de òke Efraimu, o si mu wọn pada sọdọ Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn.
5O si fi awọn onidajọ si ilẹ na, ninu gbogbo ilu olodi Juda, lati ilu de ilu,
6O si wi fun awọn onidajọ pe, Ẹ kiyesi ohun ti ẹnyin nṣe! nitori ti ẹnyin kò dajọ fun enia bikòṣe fun Oluwa, ti o wà pẹlu nyin ninu ọ̀ran idajọ.
7Njẹ nisisiyi, jẹ ki ẹ̀ru Oluwa ki o wà lara nyin, ẹ ma ṣọra, ki ẹ si ṣe e; nitoriti kò si aiṣedede kan lọdọ Oluwa Ọlọrun wa, tabi ojuṣaju enia, tabi gbigba abẹtẹlẹ.
8Pẹlupẹlu ni Jerusalemu, Jehoṣafati yàn ninu awọn ọmọ Lefi, ati ninu awọn alufa, ati ninu awọn olori awọn baba Israeli, fun idajọ Oluwa, ati fun ẹjọ; nwọn si ngbe Jerusalemu.
9O si kilọ fun wọn, wipe, Bayi ni ki ẹnyin ki o mã ṣe, ni ibẹ̀ru Oluwa, li otitọ, ati pẹlu ọkàn pipé.
10Ẹjọ ki ẹjọ ti o ba si de ọdọ nyin lati ọdọ awọn arakunrin nyin ti ngbe ilu wọn, lãrin ẹ̀jẹ on ẹ̀jẹ, lãrin ofin pẹlu aṣẹ, ìlana ati ẹtọ́, ki ẹnyin ki o kilọ fun wọn, ki nwọn ki o máṣe dẹṣẹ si Oluwa, ibinu a si wá sori nyin, ati sori awọn arakunrin nyin: ẹ ṣe bẹ̃ gẹgẹ, ẹnyin kì yio si jẹbi.
11Si wõ, Amariah, alufa ni olori lori nyin ni gbogbo ọ̀ran Oluwa; ati Sebadiah, ọmọ Iṣmaeli, alakoso ile Juda, fun ọ̀ran ọba; pẹlupẹlu ẹnyin ni olutọju awọn ọmọ Lefi pẹlu nyin. Ẹ mu ara le, ki ẹ si ṣe, Oluwa yio pẹlu ẹni-rere.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. Kro 19: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀