II. Kro 12

12
Àwọn Ará Ijipti Gbógun ti Juda
(I. A. Ọba 14:25-28)
1O si ṣe, nigbati Rehoboamu ti fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ ti o si ti mu ara rẹ̀ le, o kọ̀ ofin Oluwa silẹ, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀.
2O si ṣe ni ọdun karun Rehoboamu ọba, ni Ṣiṣaki, ọba Egipti, gòke wá si Jerusalemu, nitoriti nwọn ti dẹṣẹ si Oluwa.
3Pẹlu ẹgbẹfa kẹkẹ́, ati ọkẹ́ mẹta ẹlẹṣin: awọn enia ti o ba a ti Egipti wá kò niye; awọn ara Libia, awọn ara Sukki, ati awọn ara Etiopia.
4O si kọ́ awọn ilu olodi ti iṣe ti Juda, o si wá si Jerusalemu.
5Nigbana ni Ṣemaiah, woli, tọ̀ Rehoboamu wá, ati awọn ijoye Juda, ti o kojọ pọ̀ si Jerusalemu nitori Ṣiṣaki, o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi, enyin ti kọ̀ mi silẹ, nitorina li emi si ṣe fi nyin silẹ si ọwọ Ṣiṣaki.
6Nigbana li awọn ijoye Israeli ati ọba rẹ̀ ara wọn silẹ; nwọn si wipe: Oluwa li olododo!
7Nigbati Oluwa ri pe nwọn rẹ̀ ara wọn silẹ, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Ṣemaiah wá, wipe, Nwọn ti rẹ̀ ara wọn silẹ; nitorina emi kì o run wọn, ṣugbọn emi o fun wọn ni igbala diẹ: a kì yio dà ibinu mi sori Jerusalemu nipa ọwọ Ṣiṣaki.
8Ṣugbọn nwọn o ma ṣe iranṣẹ rẹ̀: ki nwọn ki o le mọ̀ ìsin mi, ati ìsin ijọba ilẹ wọnni.
9Bẹ̃ni Ṣiṣaki, ọba Egipti, goke wá si Jerusalemu, o si kó iṣura ile Oluwa lọ, ati iṣura ile ọba; o kó gbogbo rẹ̀: o kó awọn asà wura lọ pẹlu ti Solomoni ti ṣe.
10Rehoboamu ọba si ṣe asà idẹ ni ipò wọn, o si fi wọn le ọwọ olori ẹṣọ ti ntọju ọ̀na ile ọba.
11O si ṣe, nigbakugba ti ọba ba si wọ̀ ile Oluwa lọ, awọn ẹṣọ a de, nwọn a si kó wọn wá, nwọn a si kó wọn pada sinu iyara ẹṣọ.
12Nigbati o si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, ibinu Oluwa yipada kuro lọdọ rẹ̀, ti kò fi run u patapata: ni Juda pẹlu, ohun rere si mbẹ.
Ìjọba Rehoboamu ní ṣókí
13Bẹ̃ni Rehoboamu ọba mu ara rẹ̀ le ni Jerusalemu, o si jọba: nitori Rehoboamu jẹ ẹni ọdun mọkanlelogoji nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mẹtadinlogun ni Jerusalemu, ilu ti Oluwa ti yàn lati inu gbogbo ẹ̀ya Israeli, lati fi orukọ rẹ̀ sibẹ. Orukọ iya rẹ̀ si ni Naama, ara Ammoni.
14O si ṣe buburu, nitori ti kò mura ọkàn rẹ̀ lati wá Oluwa.
15Njẹ iṣe Rehoboamu, ti iṣaju ati ti ikẹhin, a kò ha kọ wọn sinu iwe Ṣemaiah, woli, ati ti Iddo, ariran, nipa iwe itan idile? Ọtẹ si wà lãrin Rehoboamu ati Jeroboamu nigbagbogbo.
16Rehoboamu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sìn i ni ilu Dafidi: Abijah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. Kro 12: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀