I. Tim 4
4
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Àkókò Ìyapa ninu Ẹ̀sìn
1ṢUGBỌN Ẹmí ntẹnumọ ọ pe, ni igba ikẹhin awọn miran yio kuro ninu igbagbọ́, nwọn o mã fiyesi awọn ẹmí ti ntan-ni-jẹ, ati ẹkọ́ awọn ẹmí èṣu;
2Nipa agabagebe awọn ti nṣeke, awọn ti ọkàn awọn tikarawọn dabi eyiti a fi irin gbigbona jó.
3Awọn ti nda-ni-lẹkun ati gbeyawo, ti nwọn si npaṣẹ lati ka ẽwọ onjẹ ti Ọlọrun ti da fun itẹwọgba pẹlu ọpẹ awọn onigbagbọ ati awọn ti o mọ otitọ.
4Nitori gbogbo ohun ti Ọlọrun dá li o dara, kò si ọkan ti o yẹ ki a kọ̀, bi a ba fi ọpẹ́ gbà a.
5Nitori a fi ọ̀rọ Ọlọrun ati adura yà a si mimọ́.
Òjíṣẹ́ Rere Ti Kristi Jesu
6Bi iwọ ba nrán awọn ará leti nkan wọnyi, iwọ o jẹ iranṣẹ rere ti Kristi Jesu, ti a nfi ọrọ igbagbọ́ ati ẹ̀kọ rere bọ́, eyiti iwọ ti ntẹle.
7Ṣugbọn kọ̀ ọrọ asan ati itan awọn agba obinrin, si mã tọ́ ara rẹ si ìwa-bi-Ọlọrun.
8Nitori ṣíṣe eré ìdaraya ní èrè diẹ, ṣugbọn ìwa-bi-Ọlọrun li ère fun ohun gbogbo, o ni ileri ti aiye isisiyi ati ti eyi ti mbọ̀.
9Otitọ ni ọrọ na, o si yẹ fun itẹwọgbà gbogbo.
10Nitori fun eyi li awa nṣe lãlã ti a si njijakadi, nitori awa ni ireti ninu Ọlọrun alãye, ẹniti iṣe Olugbala gbogbo enia, pẹlupẹlu ti awọn ti o gbagbọ́.
11Nkan wọnyi ni ki o mã palaṣẹ ki o si mã kọ́ni.
12Máṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o gàn ewe rẹ; ṣugbọn ki iwọ ki o jẹ apẹrẹ fun awọn ti o gbagbọ́, ninu ọ̀rọ, ninu ìwa hihu, ninu ifẹ, ninu ẹmí, ninu igbagbọ́, ninu ìwa mimọ́.
13Titi emi o fi de, mã tọju iwe kikà ati igbaniyanju ati ikọ́ni.
14Máṣe ainani ẹ̀bun ti mbẹ lara rẹ, eyiti a fi fun ọ nipa isọtẹlẹ pẹlu ifọwọle awọn àgba.
15Mã fiyesi nkan wọnyi; fi ara rẹ fun wọn patapata; ki ilọsiwaju rẹ ki o le hàn gbangba fun gbogbo enia.
16Mã ṣe itọju ara rẹ ati ẹkọ́ rẹ; mã duro laiyẹsẹ ninu nkan wọnyi: nitori ni ṣiṣe eyi, iwọ ó gbà ara rẹ ati awọn ti ngbọ́ ọ̀rọ rẹ là.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
I. Tim 4: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.