I. Sam 5
5
Àpótí Ẹ̀rí bọ́ sọ́wọ́ àwọn ará Filistia
1AWỌN Filistini si gbe Apoti Ọlọrun, nwọn si mu u lati Ebeneseri wá si Aṣdodu.
2Nigbati awọn Filistini gbe apoti Ọlọrun, nwọn si gbe e wá si ile Dagoni, nwọn gbe e kà ilẹ li ẹba Dagoni.
3Nigbati awọn ara Aṣdodu ji li owurọ ọjọ keji, kiye si i, Dagoni ti ṣubu dojubolẹ niwaju apoti Oluwa. Nwọn si gbe Dagoni, nwọn si tun fi i si ipò rẹ̀.
4Nigbati nwọn ji li owurọ̀ ọjọ keji, kiyesi i, Dagoni ti ṣubu dojubolẹ niwaju apoti Oluwa; ati ori Dagoni ati atẹlẹ ọwọ́ rẹ̀ mejeji ke kuro li oju ọ̀na; Dagoni ṣa li o kù fun ara rẹ̀.
5Nitorina awọn alufa Dagoni, ati gbogbo awọn ti ima wá si ile Dagoni, kò si tẹ oju ọ̀na Dagoni ni Aṣdodu titi di oni.
6Ọwọ́ Oluwa si wuwo si ara Aṣdodu, o si pa wọn run, o si fi iyọdi pọn wọn loju, ani Aṣdodu ati agbegbe rẹ̀.
7Nigbati awọn enia Aṣdodu ri pe bẹ̃ li o ri, nwọn si wi pe, Apoti Ọlọrun Israeli kì yio ba wa gbe: nitoripe ọwọ́ rẹ̀ wuwo si wa, ati si Dagoni ọlọrun wa.
8Nwọn ranṣẹ nitorina, nwọn si pè gbogbo awọn ijoye Filistini sọdọ wọn, nwọn bere pe, Awa o ti ṣe apoti Ọlọrun Israeli si? Nwọn si dahun pe, Ẹ jẹ ki a gbe apoti Ọlọrun Israeli lọ si Gati. Nwọn si gbe apoti Ọlọrun Israeli na lọ sibẹ.
9O si ṣe pe, lẹhin igbati nwọn gbe e lọ tan, ọwọ́ Oluwa si wà si ilu na pẹlu iparun nla, o si pọn awọn enia ilu na loju, ati ọmọde ati agbà, nwọn ni iyọdi.
10Nitorina nwọn rán apoti Ọlọrun lọ si Ekronu. O si ṣe, bi apoti Ọlọrun ti de Ekronu, bẹ̃li awọn enia Ekronu kigbe wipe, nwọn gbe apoti Ọlọrun Israeli tọ̀ ni wá, lati pa wa, ati awọn enia wa.
11Bẹ̃ni nwọn ranṣẹ, nwọn si pe gbogbo ijoye Filistini jọ, nwọn si wipe, Rán apoti Ọlọrun Israeli lọ, ki ẹ si jẹ ki o tun pada lọ si ipò rẹ̀, ki o má ba pa wa, ati awọn enia wa: nitoriti ipaiya ikú ti wà ni gbogbo ilu na; ọwọ́ Ọlọrun si wuwo gidigidi ni ibẹ.
12Awọn ọmọkunrin ti kò kú ni a si fi iyọdi pọn loju: igbe ilu na si lọ soke ọrun.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
I. Sam 5: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.