O si ṣe, nigbati Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si bọ̀ si Siklagi ni ijọ kẹta, awọn ara Amaleki si ti kọlu iha ariwa, ati Siklagi, nwọn si ti kun u; Nwọn si ko awọn obinrin ti mbẹ ninu rẹ̀ ni igbekun, nwọn kò si pa ẹnikan, ọmọde tabi agbà, ṣugbọn nwọn ko nwọn lọ, nwọn si ba ọ̀na ti nwọn lọ. Dafidi ati awọn ọmọkunrin si wọ ilu, si wõ, a ti kun u; ati obinrin wọn, ati ọmọkunrin wọn ati ọmọbinrin wọn li a kó ni igbèkun lọ. Dafidi ati awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ si gbe ohùn wọn soke, nwọn si sọkun titi agbara kò si si fun wọn mọ lati sọkun. A si kó awọn aya Dafidi mejeji nigbèkun lọ, Ahinoamu ara Jesreeli, ati Abigaili aya, Nabali ara Karmeli. Dafidi si banujẹ gidigidi, nitoripe awọn enia na si nsọ̀rọ lati sọ ọ li okuta, nitoriti inu gbogbo awọn enia na si bajẹ, olukuluku ọkunrin nitori ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati nitori ọmọ rẹ̀ obinrin: ṣugbọn Dafidi mu ara rẹ̀ li ọkàn le ninu Oluwa Ọlọrun rẹ̀. Dafidi si wi fun Abiatari alufa, ọmọ Ahimeleki pe, Emi bẹ̀ ọ, mu efodu fun mi wá nihinyi. Abiatari si mu efodu na wá fun Dafidi. Dafidi si bere lọdọ Oluwa wipe, Ki emi ki o lepa ogun yi bi? emi le ba wọn? O si da a lohùn pe, Lepa: nitoripe ni biba iwọ o ba wọn, ni gbigba iwọ o si ri wọn gbà.
Kà I. Sam 30
Feti si I. Sam 30
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Sam 30:1-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò