Ọkan ninu awọn ọmọkunrin Nabali si wi fun Abigaili aya rẹ̀ pe, Wõ, Dafidi ran onṣẹ lati aginju wá lati ki oluwa wa; o si kanra mọ wọn. Ṣugbọn awọn ọkunrin na ṣe ore fun wa gidigidi, nwọn kò ṣe wa ni iwọsi kan, ohunkohun kò nù li ọwọ́ wa, ni gbogbo ọjọ ti awa ba wọn rìn nigbati awa mbẹ li oko. Odi ni nwọn sa jasi fun wa lọsan, ati loru, ni gbogbo ọjọ ti a fi ba wọn gbe, ti a mbojuto awọn agutan. Njẹ si ro o wò, ki o si mọ̀ eyiti iwọ o ṣe; nitoripe ati gbero ibi si oluwa wa, ati si gbogbo ile rẹ̀: on si jasi ọmọ Beliali ti a ko le sọ̀rọ fun. Abigaili si yara, o si mu igba iṣu akara ati igo ọti-waini meji, ati agutan marun, ti a ti sè, ati oṣuwọn agbado yiyan marun, ati ọgọrun idi ajara, ati igba akara eso ọpọtọ, o si di wọn ru kẹtẹkẹtẹ. On si wi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe, Ma lọ niwaju mi; wõ, emi mbọ lẹhin nyin. Ṣugbọn on kò wi fun Nabali bale rẹ̀.
Kà I. Sam 25
Feti si I. Sam 25
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Sam 25:14-19
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò