I. Sam 25
25
Ikú Samuẹli
1SAMUELI si kú; gbogbo enia Israeli si ko ara wọn jọ, nwọn sì sọkun rẹ̀, nwọn si sin i ninu ile rẹ̀ ni Rama. Dafidi si dide, o si sọkalẹ lọ si ijù Parani.
2Ọkunrin kan si mbẹ ni Maoni, ẹniti iṣẹ rẹ̀ mbẹ ni Karmeli; ọkunrin na si pọ̀ gidigidi, o si ni ẹgbẹdogun agutan, ati ẹgbẹrun ewurẹ: o sì nrẹ irun agutan rẹ̀ ni Karmeli.
3Orukọ ọkunrin na si njẹ Nabali, orukọ aya rẹ̀ si njẹ Abigaili; on si jẹ oloye obinrin, ati arẹwa enia; ṣugbọn onroro ati oniwa buburu ni ọkunrin; ẹni idile Kalebu li on si ṣe.
4Dafidi si gbọ́ li aginju pe, Nabali nrẹ irun agutan rẹ̀.
5Dafidi si ran ọmọkunrin mẹwa, Dafidi si sọ fun awọn ọdọmọkunrin na pe, Ẹ goke lọ si Karmeli, ki ẹ si tọ Nabali lọ, ki ẹ si ki i li orukọ mi.
6Bayi li ẹ o si wi fun ẹniti o wà ni irọra pe, Alafia fun ọ, alafia fun ile rẹ, ati alafia fun ohun gbogbo ti iwọ ni.
7Njẹ mo gbọ́ pe, awọn olùrẹrun mbẹ lọdọ rẹ; Wõ, awọn oluṣọ agutan rẹ ti wà lọdọ wa, awa kò ṣe wọn ni iwọsi kan, bẹ̃ni ohun kan ko si nù lọwọ wọn, ni gbogbo ọjọ ti nwọn wà ni Karmeli.
8Bi awọn ọmọkunrin rẹ lere, nwọn o si sọ fun ọ. Nitorina jẹ ki awọn ọmọkunrin wọnyi ki o ri oju rere lọdọ rẹ; nitoripe awa sa wá li ọjọ rere: emi bẹ ọ, ohunkohun ti ọwọ́ rẹ ba bá, fi fun awọn iranṣẹ rẹ, ati fun Dafidi ọmọ rẹ.
9Awọn ọmọkunrin Dafidi si lọ, nwọn si sọ fun Nabali gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ wọnyi li orukọ Dafidi, nwọn si simi.
10Nabali si da awọn iranṣẹ Dafidi lohùn, pe, Tani ijẹ Dafidi? tabi tani si njẹ ọmọ Jesse? ọ̀pọlọpọ iranṣẹ ni mbẹ nisisiyi ti nwọn sá olukuluku kuro lọdọ oluwa rẹ̀.
11Njẹ ki emi ki o ha mu onjẹ mi, ati omi mi, ati ẹran mi ti mo pa fun awọn olùrẹrun mi, ki emi ki o si fi fun awọn ọkunrin ti emi kò mọ̀ ibi ti nwọn gbe ti wá?
12Bẹ̃li awọn ọmọkunrin Dafidi si mu ọ̀na wọn pọ̀n, nwọn si pada, nwọn si wá, nwọn si rò fun u gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ wọnyi.
13Dafidi si wi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe, Ki olukuluku nyin ki o di idà rẹ̀ mọ idi. Olukuluku ọkunrin si di idà rẹ̀ mọ idi; ati Dafidi pẹlu si di idà tirẹ̀: iwọn irinwo ọmọkunrin si goke tọ Dafidi lẹhin; igba si joko nibi ẹrù.
14Ọkan ninu awọn ọmọkunrin Nabali si wi fun Abigaili aya rẹ̀ pe, Wõ, Dafidi ran onṣẹ lati aginju wá lati ki oluwa wa; o si kanra mọ wọn.
15Ṣugbọn awọn ọkunrin na ṣe ore fun wa gidigidi, nwọn kò ṣe wa ni iwọsi kan, ohunkohun kò nù li ọwọ́ wa, ni gbogbo ọjọ ti awa ba wọn rìn nigbati awa mbẹ li oko.
16Odi ni nwọn sa jasi fun wa lọsan, ati loru, ni gbogbo ọjọ ti a fi ba wọn gbe, ti a mbojuto awọn agutan.
17Njẹ si ro o wò, ki o si mọ̀ eyiti iwọ o ṣe; nitoripe ati gbero ibi si oluwa wa, ati si gbogbo ile rẹ̀: on si jasi ọmọ Beliali ti a ko le sọ̀rọ fun.
18Abigaili si yara, o si mu igba iṣu akara ati igo ọti-waini meji, ati agutan marun, ti a ti sè, ati oṣuwọn agbado yiyan marun, ati ọgọrun idi ajara, ati igba akara eso ọpọtọ, o si di wọn ru kẹtẹkẹtẹ.
19On si wi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe, Ma lọ niwaju mi; wõ, emi mbọ lẹhin nyin. Ṣugbọn on kò wi fun Nabali bale rẹ̀.
20O si ṣe, bi o ti gun ori kẹtẹkẹtẹ, ti o si nsọkalẹ si ibi ikọkọ oke na, wõ, Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si nsọ-kalẹ, niwaju rẹ̀; on si wá pade wọn.
21Dafidi si ti wipe, Njẹ lasan li emi ti pa gbogbo eyi ti iṣe ti eleyi mọ li aginju, ti ohunkohun kò si nù ninu gbogbo eyi ti iṣe tirẹ̀; on li o si fi ibi san ire fun mi yi.
22Bẹ̃ ati ju bẹ̃ lọ ni ki Ọlọrun ki o ṣe si awọn ọta Dafidi, bi emi ba fi ẹnikẹni ti ntọ̀ sara ogiri silẹ ninu gbogbo eyi ti iṣe tirẹ̀ titi di imọlẹ owurọ.
23Abigaili si ri Dafidi, on si yara, o sọkalẹ lori kẹtẹkẹtẹ, o si dojubolẹ niwaju Dafidi, o si tẹ ara rẹ̀ ba silẹ.
24O si wolẹ li ẹba ẹsẹ rẹ̀ o wipe, Oluwa mi, fi ẹ̀ṣẹ yi ya mi: ki o si jẹ ki iranṣẹbinrin rẹ, emi bẹ̀ ọ, sọ̀rọ leti rẹ, ki o si gbọ́ ọ̀rọ iranṣẹbinrin rẹ.
25Oluwa mi, emi bẹ̀ ọ, má ka ọkunrin Beliali yi si, ani Nabali: nitoripe bi orukọ rẹ̀ ti jẹ bẹ̃li on na ri: Nabali li orukọ rẹ̀, aimoye si wà pẹlu rẹ̀; ṣugbọn emi iranṣẹbinrin rẹ kò ri awọn ọmọkunrin oluwa mi, ti iwọ rán.
26Njẹ, oluwa mi, bi Oluwa ti wà lãye, ati bi ẹmi rẹ si ti wà làye, bi Oluwa si ti da ọ duro lati wá ta ẹjẹ silẹ, ati lati fi ọwọ́ ara rẹ gbẹsan; njẹ, ki awọn ọta rẹ, ati awọn ẹniti ngbero ibi si oluwa mi ri bi Nabali.
27Njẹ eyi ni ẹbùn ti iranṣẹbinrin rẹ mu wá fun oluwa mi, jẹ ki a si fi fun awọn ọmọkunrin ti ntọ oluwa mi lẹhin.
28Emi bẹ̀ ọ, fi irekọja iranṣẹbinrin rẹ ji i: nitori ti Oluwa yio sa ṣe ile ododo fun oluwa mi, nitori ogun Oluwa ni oluwa mi njà; a kò si ri ibi lọwọ rẹ ni gbogbo ọjọ rẹ.
29Ọkunrin kan si dide lati ma lepa rẹ, ati lati ma wá ẹmi rẹ: ṣugbọn a o si di ẹmi oluwa mi ninu idi ìye lọdọ Oluwa Ọlọrun rẹ; ati ẹmi awọn ọta rẹ li a o si gbọ̀n sọnù gẹgẹ bi kànakana jade.
30Yio si ṣe, Oluwa yio ṣe si oluwa mi gẹgẹ bi gbogbo ire ti o ti wi nipa tirẹ, yio si yan ọ li alaṣẹ lori Israeli.
31Eyi ki yio si jasi ibinujẹ fun ọ, tabi ibinujẹ ọkàn fun oluwa mi, nitoripe iwọ ta ẹjẹ alaiṣẹ silẹ, tabi pe oluwa mi gbẹsan fun ara rẹ̀: ṣugbọn nigbati Oluwa ba ṣe ore fun oluwa mi, njẹ ranti iranṣẹbinrin rẹ.
32Dafidi si wi fun Abigaili pe, Alabukun fun Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o ran ọ loni yi lati pade mi.
33Ibukun ni fun ọgbọn rẹ, alabukunfun si ni iwọ, ti o da mi duro loni yi lati wá ta ẹjẹ silẹ, ati lati fi ọwọ́ mi gbẹsan fun ara mi.
34Nitõtọ bi Oluwa Ọlọrun Israeli ti mbẹ, ti o da mi duro lati pa ọ lara, bikoṣepe bi iwọ ti yara ti o si ti wá pade mi, nitotọ ki ba ti kù fun Nabali di imọlẹ owurọ ninu awọn ti o ntọ̀ sara ogiri.
35Bẹ̃ni Dafidi si gbà nkan ti o mu wá fun u li ọwọ́ rẹ̀, o si wi fun u pe, Goke lọ li alafia si ile rẹ, wõ, emi ti gbọ́ ohun rẹ, inu mi si dùn si ọ.
36Abigaili si tọ̀ Nabali wá, si wõ, on si se asè ni ile rẹ̀ gẹgẹ bi ase ọba; inu Nabali si dùn nitoripe, o ti mu ọti li amupara; on kò si sọ nkan fun u, diẹ tabi pupọ: titi di imọlẹ owurọ.
37O si ṣe; li owurọ, nigbati ọti na si dá tan li oju Nabali, obinrin rẹ̀ si rò nkan wọnni fun u, ọkàn rẹ̀ si kú ninu, on si dabi okuta.
38O si ṣe lẹhin iwọn ijọ mẹwa, Oluwa lù Nabali, o si kú.
39Dafidi si gbọ́ pe Nabali kú, o si wi pe, Iyin ni fun Oluwa ti o gbeja gigàn mi lati ọwọ́ Nabali wá, ti o si da iranṣẹ rẹ̀ duro lati ṣe ibi: Oluwa si yi ikà Nabali si ori on tikalarẹ̀. Dafidi si ranṣẹ, o si ba Abigaili sọ̀rọ lati mu u fi ṣe aya fun ara rẹ̀.
40Awọn iranṣẹ Dafidi si lọ sọdọ Abigaili ni Karmeli, nwọn si sọ fun u pe, Dafidi rán wa wá si ọ lati mu ọ ṣe aya rẹ̀.
41O si dide, o si dojubolẹ, o si wipe, Wõ, jẹ ki iranṣẹbinrin rẹ ki o jẹ iranṣẹ kan lati ma wẹ ẹsẹ awọn iranṣẹ oluwa mi.
42Abigaili si yara, o dide, o si gun kẹtẹkẹtẹ, awọn iranṣẹbinrin rẹ̀ marun si tẹle e lẹhin; on si tẹle awọn iranṣẹ Dafidi, o si wa di aya rẹ̀.
43Dafidi si mu Ahinoamu ti Jesreeli; awọn mejeji si jẹ aya rẹ̀.
44Ṣugbọn Saulu ti fi Mikali ọmọ rẹ̀ obinrin, aya Dafidi, fun Falti ọmọ Laisi ti iṣe ara Gallimu.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
I. Sam 25: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.