I. Sam 24:6-13

I. Sam 24:6-13 YBCV

On si wi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe, Èwọ̀ ni fun mi lati ọdọ Oluwa wá bi emi ba ṣe nkan yi si oluwa mi, ẹniti a ti fi ami ororo Oluwa yàn, lati nàwọ́ mi si i, nitoripe ẹni-ami-ororo Oluwa ni. Dafidi si fi ọ̀rọ wọnyi da awọn ọmọkunrin rẹ̀ duro, kò si jẹ ki wọn dide si Saulu. Saulu si dide kuro ni iho na, o si ba ọ̀na rẹ̀ lọ. Dafidi si dide lẹhin na, o si jade kuro ninu iho na, o si kọ si Saulu pe, Oluwa mi, ọba. Saulu si wo ẹhìn rẹ̀, Dafidi si doju rẹ̀ bo ilẹ, o si tẹriba fun u. Dafidi si wi fun Saulu pe, Eha ti ṣe ti iwọ fi ngbọ́ ọ̀rọ awọn enia pe, Wõ, Dafidi nwá ẹmi rẹ? Wõ, oju rẹ ri loni, bi Oluwa ti fi iwọ le mi li ọwọ́ loni ni iho nì: awọn kan ni ki emi ki o pa ọ: ṣugbọn emi dá ọ si; emi si wipe, emi ki yio nawọ́ mi si oluwa mi, nitoripe ẹni-ami-ororo Oluwa li on iṣe. Pẹlupẹlu, baba mi, wõ, ani wo eti aṣọ rẹ li ọwọ́ mi; nitori emi ke eti aṣọ rẹ, emi ko si pa ọ, si wò, ki o si mọ̀ pe, kò si ibi tabi ẹ̀ṣẹ li ọwọ́ mi, emi kò si ṣẹ̀ ọ, ṣugbọn iwọ ndọdẹ ẹmi mi lati gba a. Ki Oluwa ki o ṣe idajọ larin emi ati iwọ, ati ki Oluwa ki o gbẹsan mi lara rẹ; ṣugbọn ọwọ́ mi ki yio si lara rẹ. Gẹgẹ bi owe igba atijọ ti wi, Ìwabuburu a ma ti ọdọ awọn enia buburu jade wá; ṣugbọn ọwọ́ mi kì yio si lara rẹ.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú I. Sam 24:6-13