Akikanju kan si jade lati ibudo awọn Filistini wá, orukọ rẹ̀ ama jẹ Goliati, ara Gati, ẹniti giga rẹ̀ jẹ igbọnwọ mẹfa ati ibu atẹlẹwọ kan. On si ni akoro idẹ kan li ori rẹ̀, o si wọ̀ ẹ̀wu kan ti a fi idẹ pẹlẹbẹ pẹlẹbẹ ṣe, ìwọn ẹwu na si jẹ ẹgbẹdọgbọn Ṣekeli idẹ. On si ni kobita idẹ li ẹsẹ rẹ̀, ati apata idẹ kan larin ejika rẹ̀. Ọpa ọ̀kọ rẹ̀ si dabi igi awọn awunṣọ, ati ori ọ̀kọ rẹ̀ si jẹ ẹgbẹta oṣuwọn sekeli irin: ẹnikan ti o ru awà kan si nrin niwaju rẹ̀.
Kà I. Sam 17
Feti si I. Sam 17
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Sam 17:4-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò