Ọkan ninu iranṣẹ wọnni si dahùn wipe, Wõ emi ri ọmọ Jesse kan ti Betlehemu ti o mọ̀ iṣẹ orin, o si jẹ ẹni ti o li agbara gidigidi, ati ologun, ati ẹni ti o ni ọgbọ́n ọ̀rọ isọ, ati arẹwa, Oluwa si wà pẹlu rẹ̀. Saulu si ran iranṣẹ si Jesse wipe, ran Dafidi ọmọ rẹ si mi, ẹniti o nṣọ agutan. Jesse si mu kẹtẹkẹtẹ, o si di ẹrù akara le e, ati igò ọti-waini, ati ọmọ ewurẹ; o si ran wọn nipa ọwọ Dafidi ọmọ rẹ̀ si Saulu. Dafidi si tọ Saulu lọ, o si duro niwaju rẹ̀: on si fẹ ẹ gidigidi; Dafidi si wa di ẹniti nrù ihamọra rẹ̀. Saulu si ranṣẹ si Jesse pe, Jẹ ki Dafidi, emi bẹ ọ, duro niwaju mi; nitori ti o wù mi.
Kà I. Sam 16
Feti si I. Sam 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Sam 16:18-22
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò