SAMUELI si wi fun Saulu pe, Oluwa rán mi lati fi ami ororo yàn ọ li ọba, lori enia rẹ̀, lori Israeli, nitorina nisisiyi iwọ fetisi ohùn ọ̀rọ Oluwa. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, emi ranti eyi ti Amaleki ti ṣe si Israeli, bi o ti lumọ dè e li ọ̀na, nigbati on goke ti Egipti jade wá. Lọ nisisiyi ki o si kọlu Amaleki, ki o si pa gbogbo nkan wọn li aparun, má si ṣe da wọn si; ṣugbọn pa ati ọkunrin ati obinrin wọn, ọmọ kekere ati awọn ti o wà li ẹnu ọmu, malu ati agutan, ibakasiẹ ati kẹtẹkẹtẹ.
Kà I. Sam 15
Feti si I. Sam 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Sam 15:1-3
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò