Samueli si kepe Oluwa, Oluwa si ran ãra ati ojò ni ọjọ na: gbogbo enia si bẹru Oluwa pupọ ati Samueli. Gbogbo enia si wi fun Samueli pe, Gbadura si Oluwa Ọlọrun rẹ fun awọn iranṣẹ rẹ, ki awa ki o má ba kú: nitori ti awa ti fi buburu yi kun gbogbo ẹṣẹ wa ni bibere ọba fun ara wa. Samueli si wi fun awọn enia na pe, Ẹ má bẹ̀ru: ẹnyin ti ṣe gbogbo buburu yi: sibẹ ẹ má pada lẹhin Oluwa, ẹ ma fi gbogbo ọkàn nyin sin Oluwa. Ẹ máṣe yipada; nitori yio jasi itẹle ohun asan lẹhin, eyi ti kì yio ni ere; bẹ̃ni kì yio si gbanila; nitori asan ni nwọn. Nitoriti Oluwa kì yio kọ̀ awọn enia rẹ̀ silẹ nitori orukọ rẹ̀ nla: nitoripe o wu Oluwa lati fi nyin ṣe enia rẹ̀. Pẹlupẹlu bi o ṣe ti emi ni, ki a má ri i pe emi si dẹṣẹ̀ si Oluwa ni didẹkun gbadura fun nyin: emi o si kọ́ nyin li ọ̀na rere ati titọ. Ṣugbọn ẹ bẹ̀ru Oluwa, ki ẹ si fi gbogbo ọkàn nyin sin i lododo: njẹ, ẹ ronu ohun nlanla ti o ṣe fun nyin. Ṣugbọn bi ẹnyin ba hu ìwa buburu sibẹ, ẹnyin o ṣegbé t'ẹnyin t'ọba nyin.
Kà I. Sam 12
Feti si I. Sam 12
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Sam 12:18-25
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò