I. Sam 10:1-6

I. Sam 10:1-6 YBCV

SAMUELI si mu igo ororo, o si tu u si i li ori, o si fi ẹnu kò o li ẹnu, o si wipe, Kò ṣepe nitoriti Oluwa ti fi ororo yàn ọ li olori ini rẹ̀? Nigbati iwọ ba lọ kuro lọdọ mi loni, iwọ o ri ọkunrin meji li ẹba iboji Rakeli li agbegbe Benjamini, ni Selsa; nwọn o si wi fun ọ pe, Nwọn ti ri awọn kẹtẹkẹtẹ ti iwọ ti jade lọ iwá: si wõ, baba rẹ ti fi ọran ti kẹtẹkẹtẹ silẹ, o si kọ ominu nitori rẹ wipe, Kili emi o ṣe niti ọmọ mi? Iwọ o si kọja lati ibẹ lọ, iwọ o si de pẹtẹlẹ Tabori, nibẹ li ọkunrin mẹta ti nlọ sọdọ Ọlọrun ni Beteli yio pade rẹ, ọkan yio mu, ọmọ ewurẹ mẹta lọwọ, ekeji yio mu iṣù akara mẹta, ati ẹkẹta yio mu igo ọti-waini. Nwọn o si ki ọ, nwọn o si fi iṣù akara meji fun ọ; iwọ o si gbà a lọwọ wọn. Lẹhin eyini iwọ o wá si oke Ọlọrun, nibiti ẹgbẹ ogun awọn Filistini wà; yio si ṣe, nigbati iwọ ba de ilu na, iwọ o si pade ẹgbẹ woli ti yio ma sọkalẹ lati ibi giga nì wá; nwọn o si ni psalteri, ati tabreti, ati fère, ati harpu niwaju wọn, nwọn o si ma sọtẹlẹ. Ẹmi Oluwa yio si bà le ọ, iwọ o si ma ba wọn sọtẹlẹ, iwọ o si di ẹlomiran.