I. Pet 5
5
Bíbọ́ Agbo Aguntan Ọlọrun
1AWỌN alàgba ti mbẹ lãrin nyin ni mo bẹ̀, emi ẹniti iṣe alàgba bi ẹnyin, ati ẹlẹri ìya Kristi, ati alabapin ninu ogo ti a o fihàn:
2Ẹ mã tọju agbo Ọlọrun ti mbẹ lãrin nyin, ẹ mã bojuto o, kì iṣe afipáṣe, bikoṣe tifẹtifẹ; bẹni ki iṣe ọrọ ère ijẹkujẹ, ṣugbọn pẹlu ọkàn ti o mura tan.
3Bẹ̃ni ki iṣe bi ẹniti nlo agbara lori ijọ, ṣugbọn ki ẹ ṣe ara nyin li apẹrẹ fun agbo.
4Nigbati olori Oluṣọ-agutan ba si fi ara hàn, ẹnyin ó gbà ade ogo ti kì iṣá.
5Bẹ̃ pẹlu, ẹnyin ipẹ̃rẹ, ẹ tẹriba fun awọn àgba. Ani, gbogbo nyin, ẹ mã tẹriba fun ara nyin, ki ẹ si fi irẹlẹ wọ̀ ara nyin li aṣọ: nitori Ọlọrun kọ oju ija si awọn agberaga, ṣugbọn O nfi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ.
6Nitorina ẹ rẹ̀ ara nyin silẹ labẹ ọwọ́ agbara Ọlọrun, ki on ki o le gbé nyin ga li akokò.
7Ẹ mã kó gbogbo aniyan nyin le e; nitoriti on nṣe itọju nyin.
8Ẹ mã wà li airekọja, ẹ mã ṣọra; nitori Èṣu, ọtá nyin, bi kiniun ti nke ramuramu, o nrìn kãkiri, o nwá ẹniti yio pajẹ kiri:
9Ẹniti ki ẹnyin ki o kọ oju ija si pẹlu iduroṣinṣin ninu igbagbọ́, ki ẹnyin ki o mọ̀ pe ìya kanna ni awọn ara nyin ti mbẹ ninu aiye njẹ.
10Ọlọrun ore-ọfẹ gbogbo, ti o ti pè nyin sinu ogo rẹ̀ ti kò nipẹkun ninu Kristi Jesu, nigbati ẹnyin ba ti jìya diẹ, On tikarãrẹ, yio si ṣe nyin li aṣepé, yio fi ẹsẹ nyin mulẹ, yio fun nyin li agbara, yio fi idi nyin kalẹ.
11Tirẹ̀ li ogo ati agbara titi lailai. Amin.
Ìdágbére
12Nipa Silfanu, arakunrin wa olõtọ gẹgẹbi mo ti ka a si, ni mo kọwe kukuru si nyin, ti mo ngbà nyin niyanju, ti mo si njẹri pe, eyi ni otitọ ore-ọfẹ Ọlọrun: ẹ duro ṣinṣin ninu rẹ̀.
13Ijọ ti mbẹ ni Babiloni, ti a yàn pẹlu nyin, kí nyin; bẹ̃ si ni Marku ọmọ mi pẹlu.
14Ẹ fi ifẹnukonu ifẹ kí ara nyin. Amin.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
I. Pet 5: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.