Niwọnbi ẹnyin ti wẹ̀ ọkàn nyin mọ́ nipa ìgbọran nyin si otitọ nipa Ẹmí si ifẹ ará ti kò li ẹ̀tan, ẹ fẹ ọmọnikeji nyin gidigidi lati ọkàn wá. Bi a ti tun nyin bi, kì iṣe lati inu irú ti idibajẹ wá, bikoṣe eyiti ki idibajẹ, nipa ọ̀rọ Ọlọrun ti mbẹ lãye ti o si duro. Nitoripe gbogbo ẹran ara dabi koriko, ati gbogbo ogo rẹ̀ bi itanná koriko. Koriko a mã gbẹ, itanná rẹ̀ a si rẹ̀ silẹ: Ṣugbọn ọ̀rọ Oluwa duro titi lai. Ọ̀rọ yi na si ni ihinrere ti a wãsu fun nyin.
Kà I. Pet 1
Feti si I. Pet 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Pet 1:22-25
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò