Ṣugbọn bi ẹnyin o ba yipada lati mã tọ̀ mi lẹhin, ẹnyin, tabi awọn ọmọ nyin, bi ẹnyin kò si pa ofin mi mọ́, ati aṣẹ mi ti mo ti fi si iwaju nyin, ṣugbọn bi ẹ ba lọ ti ẹ si sìn awọn ọlọrun miran, ti ẹ si bọ wọn: Nigbana ni emi o ké Israeli kuro ni ilẹ ti emi fi fun wọn; ati ile yi, ti mo ti yà si mimọ́ fun orukọ mi li emi o gbe sọnù kuro niwaju mi; Israeli yio si di owe ati ifiṣẹsin lãrin gbogbo orilẹ-ède. Ati ile yi, ti o ga, ẹnu o si ya olukuluku ẹniti o kọja lẹba rẹ̀, yio si pòṣe: nwọn o si wipe; ẽṣe ti Oluwa fi ṣe bayi si ilẹ yi ati si ile yi? Nwọn o si dahùn wipe, Nitoriti nwọn kọ̀ Oluwa Ọlọrun wọn silẹ, ẹniti o mu awọn baba wọn jade ti ilẹ Egipti wá, nwọn gbá awọn ọlọrun miran mú, nwọn si bọ wọn, nwọn si sìn wọn: nitorina ni Oluwa ṣe mu gbogbo ibi yi wá sori wọn.
Kà I. A. Ọba 9
Feti si I. A. Ọba 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. A. Ọba 9:6-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò