Ṣugbọn bi ẹnyin o ba yipada lati mã tọ̀ mi lẹhin, ẹnyin, tabi awọn ọmọ nyin, bi ẹnyin kò si pa ofin mi mọ́, ati aṣẹ mi ti mo ti fi si iwaju nyin, ṣugbọn bi ẹ ba lọ ti ẹ si sìn awọn ọlọrun miran, ti ẹ si bọ wọn:
Nigbana ni emi o ké Israeli kuro ni ilẹ ti emi fi fun wọn; ati ile yi, ti mo ti yà si mimọ́ fun orukọ mi li emi o gbe sọnù kuro niwaju mi; Israeli yio si di owe ati ifiṣẹsin lãrin gbogbo orilẹ-ède.
Ati ile yi, ti o ga, ẹnu o si ya olukuluku ẹniti o kọja lẹba rẹ̀, yio si pòṣe: nwọn o si wipe; ẽṣe ti Oluwa fi ṣe bayi si ilẹ yi ati si ile yi?
Nwọn o si dahùn wipe, Nitoriti nwọn kọ̀ Oluwa Ọlọrun wọn silẹ, ẹniti o mu awọn baba wọn jade ti ilẹ Egipti wá, nwọn gbá awọn ọlọrun miran mú, nwọn si bọ wọn, nwọn si sìn wọn: nitorina ni Oluwa ṣe mu gbogbo ibi yi wá sori wọn.
O si ṣe lẹhin ogún ọdun, nigbati Solomoni ti kọ́ ile mejeji tan, ile Oluwa, ati ile ọba.
Hiramu, ọba Tire ti ba Solomoni wá igi kedari ati igi firi, ati wura gẹgẹ bi gbogbo ifẹ rẹ̀, nigbana ni Solomoni ọba fun Hiramu ni ogún ilu ni ilẹ Galili.
Hiramu si jade lati Tire wá lati wò ilu ti Solomoni fi fun u: nwọn kò si wù u.
On si wipe, Ilu kini wọnyi ti iwọ fi fun mi, arakunrin mi? O si pè wọn ni ilẹ Kabulu titi fi di oni yi.
Hiramu si fi ọgọta talenti wura ranṣẹ si ọba.
Idi awọn asìnru ti Solomoni kojọ ni eyi; lati kọ́ ile Oluwa, ati ile on tikararẹ̀, ati Millo, ati odi Jerusalemu, ati Hasori ati Megiddo, ati Geseri.
Farao, ọba Egipti ti goke lọ, o si ti kó Geseri, o si ti fi iná sun u, o si ti pa awọn ara Kenaani ti ngbe ilu na, o si fi ta ọmọbinrin rẹ̀, aya Solomoni li ọrẹ.
Solomoni si kọ́ Geseri, ati Bethoroni-isalẹ.
Ati Baalati, ati Tadmori ni aginju, ni ilẹ na.
Ati gbogbo ilu iṣura ti Solomoni ni, ati ilu kẹkẹ́ rẹ̀, ati ilu fun awọn ẹlẹsin rẹ̀, ati eyiti Solomoni nfẹ lati kọ́ ni Jerusalemu, ati ni Lebanoni, ati ni gbogbo ilẹ ijọba rẹ̀.
Gbogbo enia ti o kù ninu awọn ara Amori, ara Hitti, Perisi, Hifi ati Jebusi, ti kì iṣe ti inu awọn ọmọ Israeli.
Awọn ọmọ wọn ti o kù lẹhin wọn ni ilẹ na, ti awọn ọmọ Israeli kò le parun tũtu, awọn ni Solomoni bù iṣẹ-iru fun titi di oni yi.