I. A. Ọba 5

5
Solomoni Palẹ̀mọ́ láti Kọ́ Tẹmpili
(II. Kro 2:1-18)
1HIRAMU, ọba Tire, si rán awọn iranṣẹ rẹ̀ si Solomoni; nitoriti o ti gbọ́ pe, a ti fi ororo yàn a li ọba ni ipò baba rẹ̀: nitori Hiramu ti fẹràn Dafidi li ọjọ rẹ̀ gbogbo.
2Solomoni si ranṣẹ si Hiramu wipe,
3Iwọ mọ̀ bi Dafidi, baba mi, kò ti le kọ́ ile fun orukọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀ nitori ogun ti o wà yi i ka kiri, titi Oluwa fi fi wọn sabẹ atẹlẹsẹ rẹ̀.
4Ṣugbọn nisisiyi Oluwa Ọlọrun mi ti fun mi ni isimi niha gbogbo, bẹ̃ni kò si si ọta tabi ibi kan ti o ṣẹ̀.
5Si kiye si i, mo gbèro lati kọ́ ile kan fun orukọ Oluwa Ọlọrun mi, gẹgẹ bi Oluwa ti sọ fun Dafidi, baba mi pe, Ọmọ rẹ, ti emi o gbe kà ori itẹ́ rẹ ni ipò rẹ, on ni yio kọ́ ile na fun orukọ mi.
6Njẹ nisisiyi, paṣẹ ki nwọn ki o ke igi kedari fun mi lati Lebanoni wá, awọn ọmọ ọdọ mi yio si wà pẹlu awọn ọmọ ọdọ rẹ, iwọ ni emi o si sanwo ọyà awọn ọmọ ọdọ rẹ fun, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti iwọ o wi: nitoriti iwọ mọ̀ pe, kò si ẹnikan ninu wa ti o mọ̀ bi a ti ike igi bi awọn ara Sidoni.
7O si ṣe, nigbati Hiramu gbọ́ ọ̀rọ Solomoni, o yọ̀ pipọ, o si wipe, Olubukún li Oluwa loni, ti o fun Dafidi ni ọmọ ọlọgbọ́n lori awọn enia pupọ yi.
8Hiramu si ranṣẹ si Solomoni pe, Emi ti gbọ́ eyi ti iwọ ránṣẹ si mi, emi o ṣe gbogbo ifẹ rẹ niti igi kedari ati niti igi firi.
9Awọn ọmọ ọdọ mi yio mu igi na sọkalẹ lati Lebanoni wá si okun: emi o si fi wọn ṣọwọ si ọ ni fifó li omi okun titi de ibi ti iwọ o nà ika si fun mi, emi o si mu ki nwọn ki o ko wọn sibẹ, iwọ o si ko wọn lọ: iwọ o si ṣe ifẹ mi, lati fi onjẹ fun ile mi.
10Bẹ̃ni Hiramu fun Solomoni ni igi kedari ati igi firi gẹgẹ bi gbogbo ifẹ rẹ̀.
11Solomoni si fun Hiramu ni ẹgbãwa oṣuwọ̀n ọkà ni onjẹ fun ile rẹ̀, ati ogún oṣuwọ̀n ororo daradara; bẹ̃ni Solomoni nfi fun Hiramu li ọdọdun.
12Oluwa si fun Solomoni li ọgbọ́n gẹgẹ bi o ti wi fun u: alafia si wà lãrin Hiramu ati Solomoni; awọn mejeji si ṣe adehùn.
13Solomoni ọba, si ṣà asìnrú enia jọ ni gbogbo Israeli; awọn asìnrú na jẹ ẹgbã mẹdogun enia.
14O si ràn wọn lọ si Lebanoni, ẹgbarun loṣoṣu, li ọwọ̀-ọwọ́; nwọn wà ni Lebanoni loṣu kan, nwọn a si gbe ile li oṣu meji: Adoniramu li o si ṣe olori awọn alasìnru na.
15Solomoni si ni ẹgbã marundilogoji enia ti nru ẹrù, ọkẹ mẹrin gbẹnagbẹna lori oke;
16Laikà awọn ijoye ninu awọn ti a fi ṣe olori iṣẹ Solomoni, ẹgbẹrindilogun o le ọgọrun enia, ti o nṣe alaṣẹ awọn enia ti nṣisẹ na.
17Ọba si paṣẹ, nwọn si mu okuta wá, okuta iyebiye, ati okuta gbígbẹ lati fi ipilẹ ile na le ilẹ.
18Awọn akọle Solomoni, ati awọn akọle Hiramu si gbẹ́ wọn, ati awọn ara Gebali: nwọn si pèse igi ati okuta lati kọ́ ile na.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. A. Ọba 5: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀