O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, Naboti, ara Jesreeli, ni ọgba-ajara ti o wà ni Jesreeli, ti o sunmọ ãfin Ahabu, ọba Samaria girigiri.
Ahabu si ba Naboti sọ wipe, Fun mi ni ọgba-ajara rẹ, ki emi ki o fi ṣe ọgba-ewebẹ̀, nitori ti o sunmọ ile mi: emi o si fun ọ li ọgba-ajara ti o san jù u lọ dipò rẹ̀; bi o ba si dara li oju rẹ, emi o fi iye-owo rẹ̀ fun ọ.
Naboti si wi fun Ahabu pe, Oluwa má jẹ ki emi fi ogún awọn baba mi fun ọ.
Ahabu si wá si ile rẹ̀, o wugbọ, inu rẹ̀ si bajẹ nitori ọ̀rọ ti Naboti, ara Jesreeli, sọ fun u: nitoriti on ti wipe, emi kì o fun ọ ni ogún awọn baba mi. On si dubulẹ lori akete rẹ̀, o si yi oju rẹ̀ padà, kò si fẹ ijẹun.
Jesebeli, aya rẹ̀ si tọ̀ ọ wá o si wi fun u pe, Ẽṣe ti inu rẹ fi bajẹ́ ti iwọ kò fi jẹun?
O si wi fun u pe, Nitoriti mo ba Naboti, ara Jesreeli sọ, mo si wi fun u pe, Fun mi ni ọgba-àjara rẹ fun owo; tabi bi o ba wù ọ, emi o fun ọ ni ọgba-àjara miran ni ipò rẹ̀: o si dahùn wipe, Emi kì o fun ọ ni ọgba-àjara mi.
Jesebeli, aya rẹ̀ si wi fun u pe, iwọ kò ha jọba lori Israeli nisisiyi? Dide, jẹun, ki o si jẹ ki inu rẹ ki o dùn! emi o fun ọ ni ọgba-àjara Nãboti ara Jesreeli.
Bẹ̃ni o kọwe li orukọ Ahabu, o si fi èdidi rẹ̀ di i, o si fi iwe na ṣọwọ sọdọ awọn àgbagba ati awọn ọlọla ti mbẹ ni ilu rẹ̀, ti o si mba Naboti gbe.
O si kọ sinu iwe na pe, Ẹ kede àwẹ, ki ẹ si fi Naboti si ipò ọla lãrin awọn enia.
Ki ẹ fi enia meji, ẹni buburu, siwaju rẹ̀ lati jẹri pa a, wipe, Iwọ bu Ọlọrun ati ọba. Ẹ mu u jade, ki ẹ si sọ ọ li okuta ki o le kú.
Awọn ọkunrin ilu rẹ̀, ati awọn àgbagba, ati awọn ọlọla ti nwọn iṣe ara-ilu rẹ̀, ṣe bi Jesebeli ti ranṣẹ si wọn, gẹgẹ bi a ti kọ ọ sinu iwe ti o ti fi ranṣẹ si wọn.
Nwọn si kede àwẹ, nwọn si fi Naboti si ipò ọla lãrin awọn enia.
Ọkunrin meji si de, awọn ẹni buburu, nwọn si joko niwaju rẹ̀: awọn ọkunrin buburu si jẹri pa a, ani si Naboti, niwaju awọn enia wipe: Naboti bu Ọlọrun ati ọba. Nigbana ni nwọn mu u jade kuro ni ilu, nwọn si sọ ọ li okuta, o si kú.
Nigbana ni nwọn ranṣẹ si Jesebeli wipe, A sọ Naboti li okuta, o si kú.
O si ṣe, nigbati Jesebeli gbọ́ pe, a sọ Naboti li okuta, o si kú, Jesebeli sọ fun Ahabu pe, Dide! ki o si jogun ọgba-ajara Naboti, ara Jesreeli, ti o kọ̀ lati fi fun ọ fun owo; nitori Naboti kò si lãye ṣugbọn o kú.
O si ṣe, nigbati Ahabu gbọ́ pe, Naboti kú, ni Ahabu dide lati sọkalẹ lọ si ọgba-ajara Naboti, ara Jesreeli lati jogun rẹ̀.
Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Elijah, ara Tiṣbi wá wipe,
Dide, sọkalẹ, lọ ipade Ahabu, ọba Israeli, ti o wà ni Samaria: wò o, o wà ni ọgba-ajara Naboti, nibiti o sọkalẹ lọ lati jogun rẹ̀.
Iwọ o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi: Iwọ ti pa, iwọ si ti jogun pẹlu? Iwọ o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi pe, Ni ibi ti ajá gbe lá ẹ̀jẹ Naboti, ni awọn ajá yio lá ẹ̀jẹ rẹ, ani tirẹ.