I. A. Ọba 19:9-16

I. A. Ọba 19:9-16 YBCV

O si de ibẹ̀, si ibi ihò okuta, o si wọ̀ sibẹ, si kiyesi i, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Kini iwọ nṣe nihinyi, Elijah? On si wipe, Ni jijowu emi ti njowu fun Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun: nitoriti awọn ọmọ Israeli ti kọ̀ majẹmu rẹ silẹ, nwọn ti wó awọn pẹpẹ rẹ lulẹ, nwọn si ti fi idà pa awọn woli rẹ: ati emi, ani emi nikanṣoṣo li o kù, nwọn si nwá ẹmi mi lati gba a kuro. O si wipe, Jade lọ, ki o si duro lori oke niwaju Oluwa. Si kiyesi i, Oluwa kọja, ìji nla ati lile si fà awọn oke nla ya, o si fọ́ awọn apata tũtu niwaju Oluwa; ṣugbọn Oluwa kò si ninu iji na: ati lẹhin iji na, isẹlẹ; ṣugbọn Oluwa kò si ninu isẹlẹ na. Ati lẹhin isẹlẹ na, iná; ṣugbọn Oluwa kò si ninu iná na, ati lẹhin iná na, ohùn kẹ́lẹ kekere. O si ṣe, nigbati Elijah gbọ́, o si fi agbáda rẹ̀ bo oju rẹ̀, o si jade lọ, o duro li ẹnu iho okuta na. Si kiyesi i, ohùn kan tọ̀ ọ wá wipe, Kini iwọ nṣe nihinyi Elijah? On si wipe, Ni jijowu, emi ti njowu fun Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun: nitoriti awọn ọmọ Israeli ti kọ̀ majẹmu rẹ silẹ, nwọn si ti wó awọn pẹpẹ rẹ lulẹ, nwọn si ti fi idà pa awọn woli rẹ; ati emi, ani emi nikanṣoṣo li o kù; nwọn si nwá ẹmi mi lati gba a kuro. Oluwa si wi fun u pe, Lọ, pada li ọ̀na rẹ, kọja li aginju si Damasku: nigbati iwọ ba de ibẹ, ki o si fi ororo yan Hasaeli li ọba lori Siria. Ati Jehu, ọmọ Nimṣi ni iwọ o fi ororo yàn li ọba lori Israeli: ati Eliṣa, ọmọ Ṣafati, ara Abel-Mehola ni iwọ o fi ororo yan ni woli ni ipò rẹ.