ELIJAH ara Tiṣbi, lati inu awọn olugbe Gileadi, wi fun Ahabu pe, Bi Oluwa Ọlọrun ti wà, niwaju ẹniti emi duro, kì yio si ìri tabi òjo li ọdun wọnyi, ṣugbọn gẹgẹ bi ọ̀rọ mi. Ọrọ Oluwa si tọ̀ ọ wá wipe: Kuro nihin, ki o si kọju siha ila-õrun, ki o si fi ara rẹ pamọ nibi odò Keriti, ti mbẹ niwaju Jordani. Yio si ṣe, iwọ o mu ninu odò na; mo si ti paṣẹ fun awọn ẹiyẹ iwò lati ma bọ́ ọ nibẹ. O si lọ, o si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa: o si lọ, o si ngbe ẹ̀ba odò Keriti, ti mbẹ niwaju Jordani. Awọn ẹiyẹ iwò si mu akara pẹlu ẹran fun u wá li owurọ, ati akara ati ẹran li alẹ: on si mu ninu odò na. O si ṣe lẹhin ọjọ wọnni, odò na si gbẹ, nitoriti kò si òjo ni ilẹ na.
Kà I. A. Ọba 17
Feti si I. A. Ọba 17
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. A. Ọba 17:1-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò