NJẸ li ọdun kejidilogun Jeroboamu ọba, ọmọ Nebati, Abijah jọba lori Juda. Ọdun mẹta li o jọba ni Jerusalemu: orukọ iya rẹ̀ si ni Maaka, ọmọbinrin Abiṣalomu. O si rin ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ baba rẹ̀, ti o ti dá niwaju rẹ̀: ọkàn rẹ̀ kò si pé pẹlu Oluwa Ọlọrun rẹ̀ gẹgẹ bi ọkàn Dafidi baba rẹ̀. Ṣugbọn nitori Dafidi li Oluwa Ọlọrun rẹ̀ fun u ni imọlẹ kan ni Jerusalemu, lati gbé ọmọ rẹ̀ ró lẹhin rẹ̀, ati lati fi idi Jerusalemu mulẹ: Nitori Dafidi ṣe eyi ti o tọ li oju Oluwa, kò si yipada kuro ninu gbogbo eyiti o paṣẹ fun u li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo, bikoṣe ni kiki ọ̀ran Uriah, ara Hitti. Ogun si wà lãrin Rehoboamu ati Jeroboamu li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo. Njẹ iyokù iṣe Abijah ati gbogbo eyiti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? Ogun si wà lãrin Abijah ati Jeroboamu. Abijah si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; nwọn si sin i ni ilu Dafidi: Asa, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.
Kà I. A. Ọba 15
Feti si I. A. Ọba 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. A. Ọba 15:1-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò