I. A. Ọba 12

12
Àwọn ẹ̀yà apá ìhà àríwá dìtẹ̀, wọ́n sì ya
(II. Kro 10:1-19)
1REHOBOAMU si lọ si Ṣekemu, nitori gbogbo Israeli li o wá si Ṣekemu lati fi i jẹ ọba.
2O si ṣe, nigbati Jeroboamu, ọmọ Nebati, ti o wà ni Egipti sibẹ gbọ́, nitori ti o ti sá kuro niwaju Solomoni ọba, Jeroboamu si joko ni Egipti.
3Nwọn si ranṣẹ pè e, ati Jeroboamu ati gbogbo ijọ Israeli wá, nwọn si sọ fun Rehoboamu wipe,
4Baba rẹ sọ àjaga wa di wuwo: njẹ nitorina, ṣe ki ìsin baba rẹ ti o le, ati àjaga rẹ̀ ti o wuwo, ti o fi si wa li ọrùn, ki o fẹrẹ̀ diẹ, awa o si sìn ọ.
5O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ na titi di ijọ mẹta, nigbana ni ki ẹ pada tọ̀ mi wá. Awọn enia na si lọ.
6Rehoboamu ọba si ba awọn àgbagba, ti imã duro niwaju Solomoni, baba rẹ̀, nigbati o wà lãye, gbimọ̀ wipe, Imọran kili ẹnyin dá, ki emi ki o lè da awọn enia yi lohùn?
7Nwọn si wi fun u pe, Bi iwọ o ba jẹ iranṣẹ fun awọn enia yi loni, ti iwọ o si sin wọn, ti iwọ o si da wọn lohùn, ati ti iwọ o sọ̀rọ rere fun wọn, nwọn o ṣe iranṣẹ rẹ titi lai.
8Ṣugbọn o kọ̀ ìmọran awọn àgbagba ti nwọn ba a dá, o si ba awọn ipẹrẹ ti nwọn dagba pẹlu rẹ̀, ti nwọn si duro niwaju rẹ̀ gbimọ̀.
9O si wi fun wọn pe, Imọran kini ẹnyin dá ki awa ki o le dá awọn enia yi lohùn, ti nwọn ba mi sọ wipe, Ṣe ki àjaga ti baba rẹ fi si wa lọrùn ki o fuyẹ diẹ?
10Awọn ipẹrẹ ti o dagba pẹlu rẹ̀ wi fun u pe, Bayi ni ki iwọ ki o wi fun awọn enia yi ti nwọn ba ọ sọ wipe, Baba rẹ mu ki àjaga wa di wuwo, sugbọn iwọ mu ki o fuyẹ diẹ fun wa; bayi ni ki iwọ ki o sọ fun wọn: ọmọdirin mi yio nipọn jù ẹgbẹ́ baba mi lọ.
11Njẹ nisisiyi, baba mi ti gbe àjaga wuwo kà nyin, emi o si fi kún àjaga nyin: baba mi ti fi paṣan nà nyin, sugbọn emi o fi akẽke nà nyin.
12Bẹ̃ni Jeroboamu ati gbogbo awọn enia na wá sọdọ Rehoboamu ni ijọ kẹta, gẹgẹ bi ọba ti dá wipe, Ẹ pada tọ̀ mi wá ni ijọ kẹta.
13Ọba si da awọn enia li ohùn akọ, o si kọ̀ ìmọran awọn àgbagba ti nwọn ba a dá.
14O si sọ fun wọn gẹgẹ bi ìmọran awọn ipẹrẹ wipe, Baba mi mu ki àjaga nyin ki o wuwo, emi o si bù kún àjaga nyin: baba mi fi paṣan nà nyin, ṣugbọn akẽke li emi o fi nà nyin,
15Ọba kò si fi eti si ti awọn enia na; nitoriti ọ̀ran na ati ọwọ Oluwa wá ni, ki o le mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ, ti Oluwa ti ọwọ Ahijah, ara Ṣilo, sọ fun Jeroboamu, ọmọ Nebati.
16Bẹ̃ni nigbati gbogbo Israeli ri pe, ọba kò fetisi ti wọn, awọn enia na da ọba li ohùn wipe: Ipin kini awa ni ninu Dafidi? bẹ̃ni awa kò ni iní ninu ọmọ Jesse: Israeli, ẹ pada si agọ nyin: njẹ mã bojuto ile rẹ, Dafidi! Bẹ̃ni Israeli pada sinu agọ wọn.
17Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli ti ngbe inu ilu Juda wọnni, Rehoboamu jọba lori wọn.
18Nigbana ni Rehoboamu ọba, ran Adoramu ẹniti iṣe olori iṣẹ-iru; gbogbo Israeli si sọ ọ li okuta, o si kú. Nitorina Rehoboamu, ọba yara lati gun kẹkẹ́ rẹ̀, lati sá lọ si Jerusalemu.
19Bẹ̃ni Israeli ṣọtẹ̀ si ile Dafidi titi di oni yi.
20O si ṣe nigbati gbogbo Israeli gbọ́ pe Jeroboamu tun pada bọ̀, ni nwọn ranṣẹ, nwọn si pè e wá si ajọ, nwọn si fi i jọba lori gbogbo Israeli: kò si ẹnikan ti o tọ̀ ile Dafidi lẹhin, bikoṣe kiki ẹya Juda.
Àsọtẹ́lẹ̀ Ṣemaaya
(II. Kro 11:1-4)
21Nigbati Rehoboamu si wá si Jerusalemu, o ko gbogbo ile Juda jọ, pẹlu ẹya Benjamini, ọkẹ mẹsan enia ti a yàn, ti nwọn iṣe ologun, lati ba ile Israeli ja, lati mu ijọba na pada bọ̀ sọdọ Rehoboamu, ọmọ Solomoni.
22Ṣugbọn ọ̀rọ Ọlọrun tọ̀ Ṣemaiah, enia Ọlọrun wá wipe,
23Sọ fun Rehoboamu, ọmọ Solomoni, ọba Juda, ati fun gbogbo ile Juda ati Benjamini, ati fun iyokù awọn enia wipe,
24Bayi li Oluwa wi, Ẹnyin kò gbọdọ goke bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ba awọn arakunrin nyin jà: ẹ pada olukuluku si ile rẹ̀; nitori nkan yi ati ọdọ mi wá ni. Nwọn si gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, nwọn si pada lati lọ, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa.
Jeroboamu yipada kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun
25Nigbana ni Jeroboamu kọ́ Ṣekemu li oke Efraimu o si ngbe inu rẹ̀; o si jade lati ibẹ lọ, o si kọ́ Penueli.
26Jeroboamu si wi li ọkàn rẹ̀ pe, Nisisiyi ni ijọba na yio pada si ile Dafidi:
27Bi awọn enia wọnyi ba ngoke lọ lati ṣe irubọ ni ile Oluwa ni Jerusalemu, nigbana li ọkàn awọn enia yi yio tun yipada sọdọ oluwa wọn, ani sọdọ Rehoboamu, ọba Juda, nwọn o si pa mi, nwọn o si tun pada tọ̀ Rehoboamu, ọba Juda lọ.
28Ọba si gbìmọ, o si ya ẹgbọ̀rọ malu wura meji, o si wi fun wọn pe, O pọ̀ju fun nyin lati mã goke lọ si Jerusalemu: Israeli, wò awọn ọlọrun rẹ, ti o mu ọ lati ilẹ Egipti wá!
29O si gbe ọkan kalẹ ni Beteli, ati ekeji li o fi si Dani.
30Nkan yi si di ẹ̀ṣẹ: nitori ti awọn enia lọ lati sìn niwaju ọkan, ani titi de Dani.
31O si kọ́ ile ibi giga wọnni, o si ṣe alufa lati inu awọn enia, ti kì iṣe inu awọn ọmọ Lefi.
Ọlọrun Lòdì sí Ìsìn Bẹtẹli
32Jeroboamu si dá àse silẹ li oṣu kẹjọ, li ọjọ kẹdogun oṣu, gẹgẹ bi àse ti o wà ni Juda, o si gun ori pẹpẹ na lọ: bẹ̃ni o si ṣe ni Beteli, o rubọ si awọn ọmọ-malu ti o ṣe: o si fi awọn alufa ibi giga wọnni ti o ti ṣe si Beteli.
33O si gun ori pẹpẹ na lọ ti o ti ṣe ni Beteli li ọjọ kẹdogun oṣu kẹjọ, li oṣu ti o rò li ọkàn ara rẹ̀; o si da àse silẹ fun awọn ọmọ Israeli; o si gun ori pẹpẹ na lọ, lati fi turari jona.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. A. Ọba 12: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀