OLUKULUKU ẹniti o ba gbagbọ́ pe Jesu ni Kristi, a bí i nipa ti Ọlọrun: ati gbogbo ẹniti o fẹran ẹniti o bí ni, o fẹran ẹniti a bí nipasẹ rẹ̀ pẹlu. Nipa eyi li awa mọ̀ pe awa fẹran awọn ọmọ Ọlọrun, nigbati awa fẹran Ọlọrun, ti a si npa ofin rẹ̀ mọ́. Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, pe ki awa ki o pa ofin rẹ̀ mọ́: ofin rẹ̀ kò si nira. Nitori olukuluku ẹniti a bí nipa ti Ọlọrun o ṣẹgun aiye: eyi si ni iṣẹgun ti o ṣẹgun aiye, ani igbagbọ́ wa. Tani ẹniti o ṣẹgun aiye, bikoṣe ẹniti o gbagbọ́ pe Ọmọ Ọlọrun ni Jesu iṣe? Eyi li ẹniti o wá, pẹlu omi ati ẹjẹ̀, ani Jesu Kristi, kì iṣe pẹlu omi nikan, bikoṣe pẹlu omi ati ẹ̀jẹ. Ẹmí li o si njẹri, nitoripe otitọ li Ẹmí. Nitoripe awọn mẹta li o njẹri li ọrun, Baba, Ọrọ̀, ati Ẹmi Mimọ; awọn mẹtẹ̃ta yi si jẹ ọ̀kan. Nitoripe awọn mẹta li o njẹri, Ẹmí, ati omi, ati ẹ̀jẹ: awọn mẹtẹ̃ta sì fi ohun ṣọkan. Bi awa ba ngbà ẹ̀rí enia, ẹ̀rí Ọlọrun tobi ju: nitọri ẹri Ọlọrun li eyi pe O ti jẹri niti Ọmọ rẹ̀.
Kà I. Joh 5
Feti si I. Joh 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Joh 5:1-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò