I. Joh 4:1-9

Verse Image for I. Joh 4:1-9

I. Joh 4:1-9 - OLUFẸ, ẹ máṣe gbà gbogbo ẹmí gbọ́, ṣugbọn ẹ dán awọn ẹmí wò bi nwọn ba ṣe ti Ọlọrun: nitori awọn woli eke pupọ̀ ti jade lọ sinu aiye.
Eyi li ẹ o fi mọ̀ Ẹmí Ọlọrun: gbogbo ẹmí ti o ba jẹwọ pe, Jesu Kristi wá ninu ara, ti Ọlọrun ni:
Gbogbo ẹmí ti kò si jẹwọ pe, Jesu Kristi wá ninu ara, kì iṣe ti Ọlọrun: eyi si li ẹmí Aṣodisi-Kristi na, ti ẹnyin ti gbọ́ pe o mbọ̀, ati nisisiyi o si ti de sinu aiye.
Ẹnyin ọmọ mi, ti Ọlọrun li ẹnyin, ẹnyin si ti ṣẹgun wọn: nitori ẹniti mbẹ ninu nyin tobi jù ẹniti mbẹ ninu aiye lọ.
Ti aiye ni nwọn, nitorina ni nwọn ṣe nsọrọ bi ẹni ti aiye, aiye si ngbọ́ ti wọn.
Ti Ọlọrun li awa: ẹniti o ba mọ̀ Ọlọrun o ngbọ́ ti wa: ẹniti kì ba nṣe ti Ọlọrun kò ngbọ́ ti wa. Nipa eyi li awa mọ̀ ẹmí otitọ, ati ẹmí eke.

Olufẹ, ẹ jẹ ki a fẹràn ara wa: nitori ifẹ ti ọdọ Ọlọrun wá; ati gbogbo ẹniti o ba ni ifẹ, a bí i nipa ti Ọlọrun, o si mọ̀ Ọlọrun.
Ẹniti kò ba ni ifẹ kò mọ̀ Ọlọrun: nitoripe ifẹ ni Ọlọrun.
Nipa eyi li a gbé fi ifẹ Ọlọrun hàn ninu wa, nitoriti Ọlọrun rán Ọmọ bíbi rẹ̀ nikanṣoṣo si aiye, ki awa ki o le yè nipasẹ rẹ̀.