Eyiti awa ti ri, ti awa si ti gbọ́ li awa nsọ fun nyin, ki ẹnyin pẹlu ki o le ní ìdapọ pẹlu wa: nitõtọ ìdapọ wa si mbẹ pẹlu Baba, ati pẹlu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi. Awa si kọwe nkan wọnyi si nyin, ki ayọ̀ nyin ki o le di kikún. Eyi si ni iṣẹ ti awa ti gbọ́ lẹnu rẹ̀ ti awa si njẹ́ fun nyin, pe imọlẹ li Ọlọrun, òkunkun kò si sí lọdọ rẹ̀ rara. Bi awa ba wipe awa ní ìdapọ pẹlu rẹ̀, ti awa si nrìn ninu òkunkun, awa nṣeke, awa kò si ṣe otitọ: Ṣugbọn bi awa ba nrìn ninu imọlẹ, bi on ti mbẹ ninu imọlẹ, awa ní ìdapọ pẹlu ara wa, ẹ̀jẹ Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀ ni nwẹ̀ wa nù kuro ninu ẹṣẹ gbogbo.
Kà I. Joh 1
Feti si I. Joh 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Joh 1:3-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò