EYITI o ti wà li àtetekọṣe, ti awa ti gbọ́, ti awa ti fi oju wa ri, ti awa si ti tẹjumọ, ti ọwọ́ wa si ti dìmu, niti Ọrọ ìye; (Ìye na si ti farahàn, awa si ti ri i, awa si njẹri, awa si nsọ ti ìye ainipẹkun na fun nyin, ti o ti mbẹ lọdọ Baba, ti o si farahàn fun wa;) Eyiti awa ti ri, ti awa si ti gbọ́ li awa nsọ fun nyin, ki ẹnyin pẹlu ki o le ní ìdapọ pẹlu wa: nitõtọ ìdapọ wa si mbẹ pẹlu Baba, ati pẹlu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi. Awa si kọwe nkan wọnyi si nyin, ki ayọ̀ nyin ki o le di kikún.
Kà I. Joh 1
Feti si I. Joh 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Joh 1:1-4
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò