I. Kor 7
7
Èrò Nípa Igbeyawo
1NJẸ niti awọn ohun ti ẹ ti kọwe: O dara fun ọkunrin ki o má fi ọwọ kàn obinrin.
2Ṣugbọn nitori àgbere, ki olukuluku ki o ni aya tirẹ̀, ati ki olukuluku ki o si ni ọkọ tirẹ̀.
3Ki ọkọ ki o mã ṣe ohun ti o yẹ si aya: bẹ̃ gẹgẹ si li aya pẹlu si ọkọ.
4Aya kò li agbara lori ara rẹ̀, bikoṣe ọkọ: bẹ̃ gẹgẹ li ọkọ pẹlu kò si li agbara lori ara rẹ̀, bikoṣe aya.
5Ẹ máṣe fà sẹhin kuro lọdọ ara nyin, bikoṣe nipa ifimọṣọkan, ki ẹnyin ki o le fi ara nyin fun àwẹ ati adura; ki ẹnyin ki o si tún jùmọ pade, ki Satani ki o máṣe dán nyin wò nitori aimaraduro nyin.
6Ṣugbọn mo sọ eyi bi imọran, kì iṣe bi aṣẹ.
7Nitori mo fẹ ki gbogbo enia ki o dabi emi tikarami. Ṣugbọn olukuluku enia ni ẹ̀bun tirẹ̀ lati ọdọ Ọlọrun wá, ọkan bi irú eyi, ati ekeji bi irú eyini.
8Ṣugbọn mo wi fun awọn apọ́n ati opó pe, O dara fun wọn bi nwọn ba wà gẹgẹ bi emi ti wà.
9Ṣugbọn bi nwọn kò bá le maraduro, ki nwọn ki o gbeyawo: nitori o san lati gbeyawo jù ati ṣe ifẹkufẹ lọ.
10Ṣugbọn awọn ti o ti gbeyawo ni mo si paṣẹ fun, ṣugbọn kì iṣe emi, bikoṣe Oluwa, Ki aya máṣe fi ọkọ rẹ̀ silẹ.
11Ṣugbọn bi o bá si fi i silẹ ki o wà li ailọkọ, tabi ki o ba ọkọ rẹ̀ làja: ki ọkọ ki o máṣe kọ̀ aya rẹ̀ silẹ.
12Ṣugbọn awọn iyokù ni mo wi fun, kì iṣe Oluwa: bi arakunrin kan ba li aya ti kò gbagbọ́, bi inu rẹ̀ ba si dùn lati mã ba a gbé, ki on máṣe kọ̀ ọ silẹ.
13Ati obinrin ti o ni ọkọ ti kò gbagbọ́, bi inu rẹ̀ ba si dùn lati mã ba a gbé, ki on máṣe fi i silẹ.
14Nitoriti a sọ alaigbagbọ́ ọkọ na di mimọ́ ninu aya rẹ̀, a si sọ alaigbagbọ́ aya na di mimọ́ ninu ọkọ rẹ̀: bikoṣe bẹ̃ awọn ọmọ nyin iba jẹ alaimọ́; ṣugbọn nisisiyi nwọn di mimọ́.
15Ṣugbọn bi alaigbagbọ́ na ba lọ, jẹ ki o mã lọ. Arakunrin tabi arabinrin kan kò si labẹ ìde, nitori irú ọ̀ran bawọnni: ṣugbọn Ọlọrun pè wa si alafia.
16Nitori iwọ ti ṣe mọ̀, iwọ aya, bi iwọ ó gbà ọkọ rẹ là? tabi iwọ ti ṣe mọ̀, iwọ ọkọ, bi iwọ ó gbà aya rẹ là?
Ipò tí Ọlọrun Yàn fún Ẹnìkọ̀ọ̀kan
17Ṣugbọn gẹgẹ bi Ọlọrun ti pín fun olukuluku enia, bi Oluwa ti pè olukuluku, bẹ̃ni ki o si mã rìn. Bẹ̃ni mo si nṣe ìlana ninu gbogbo ijọ.
18A ha pè ẹnikan ti o ti kọla? ki o má si ṣe di alaikọla. A ha pè ẹnikan ti kò kọla? ki o máṣe kọla.
19Ikọla ko jẹ nkan, ati aikọla kò jẹ nkan, bikoṣe pipa ofin Ọlọrun mọ́.
20Ki olukuluku enia duro ninu ìpe nipasẹ eyi ti a ti pè e.
21A ha pè ọ, nigbati iwọ jẹ ẹrú? máṣe kà a si: ṣugbọn bi iwọ ba le di omnira, kuku ṣe eyini.
22Nitori ẹniti a pè ninu Oluwa, ti iṣe ẹrú, o di ẹni omnira ti Oluwa: gẹgẹ bẹ̃ li ẹniti a pè ti o jẹ omnira, o di ẹrú Kristi.
23A ti rà nyin ni iye kan; ẹ máṣe di ẹrú enia.
24Ará, ki olukuluku enia, ninu eyi ti a pè e, ki o duro ninu ọkanna pẹlu Ọlọrun.
Ọ̀rọ̀ fún Àwọn Tí Kò Tíì Ṣe Igbeyawo ati Àwọn Opó
25Ṣugbọn nipa ti awọn wundia, emi kò ni aṣẹ Oluwa: ṣugbọn mo fun nyin ni imọran bi ẹniti o ri ãnu Oluwa gbà lati jẹ olododo.
26Nitorina mo rò pe eyi dara nitori wahalà isisiyi, eyini ni pe, o dara fun enia ki o wà bẹ̃.
27A ti dè ọ mọ́ aya ri bi? máṣe wá ọ̀na lati tú kuro. A ti tú ọ kuro lọwọ aya bi? máṣe wá aya ni.
28Ṣugbọn bi iwọ ba si gbeyawo, iwọ kò dẹṣẹ: bi a ba si gbé wundia ni iyawo, on kò dẹṣẹ. Ṣugbọn irú awọn wọnni yio ni wahalà nipa ti ara: ṣugbọn mo dá nyin si.
29Ṣugbọn eyi ni mo wi, ará, pe kukuru li akokò: lati isisiyi lọ pe ki awọn ti o li aya ki o dabi ẹnipe nwọn kò ni rí;
30Ati awọn ti nsọkun, bi ẹ́nipe nwọn kò sọkun rí; ati awọn ti nyọ̀, bi ẹnipe nwọn kò yọ̀ rí; ati awọn ti nrà, bi ẹnipe nwọn kò ni rí;
31Ati awọn ti nlò ohun aiye yi bi ẹniti kò ṣaṣeju: nitori aṣa aiye yi nkọja lọ.
32Ṣugbọn emi nfẹ ki ẹnyin ki o wà laiṣe aniyàn. Ẹniti kò gbeyawo ama tọju ohun ti iṣe ti Oluwa, bi yio ti ṣe le wù Oluwa:
33Ṣugbọn ẹniti o gbeyawo ama ṣe itọju ohun ti iṣe ti aiye, bi yio ti ṣe le wù aya rẹ̀.
34Iyatọ si wà pẹlu larin obinrin ti a gbe ni iyawo ati wundia. Obinrin ti a kò gbe ni iyawo a mã tọju ohun ti iṣe ti Oluwa, ki on ki o le jẹ mimọ́ li ara ati li ẹmí: ṣugbọn ẹniti a gbé ni iyawo a ma tọju ohun ti iṣe ti aiye, bi yio ti ṣe le wù ọkọ rẹ̀.
35Eyi ni mo si nwi fun ère ara nyin; kì iṣe lati dẹkun fun nyin, ṣugbọn nitori eyi ti o tọ́, ati ki ẹnyin ki o le mã sin Oluwa laisi ìyapa-ọkàn.
36Ṣugbọn bi ẹnikan ba rò pe on kò ṣe ohun ti o yẹ si wundia ọmọbinrin rẹ̀, bi o ba ti di obinrin, bi o ba si tọ bẹ̃, jẹ ki o ṣe bi o ti fẹ, on kò dẹṣẹ: jẹ ki nwọn gbé iyawo.
37Ṣugbọn ẹniti o duro ṣinṣin ni ọkàn rẹ̀, ti ko ni aigbọdọ máṣe, ṣugbọn ti o li agbara lori ifẹ ara rẹ̀, ti o si ti pinnu li ọkàn rẹ̀ pe, on o pa wundia ọmọbinrin on mọ́, yio ṣe rere.
38Bẹ̃ si li ẹniti o fi wundia ọmọbinrin funni ni igbeyawo, o ṣe rere: ṣugbọn ẹniti kò fi funni ni igbeyawo ṣe rere jù.
39A fi ofin dè obinrin niwọn igbati ọkọ rẹ̀ ba wà lãye; ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba kú, o di omnira lati ba ẹnikẹni ti o wù u gbeyawo; kìki ninu Oluwa.
40Ṣugbọn gẹgẹ bi imọ̀ mi, alabukun-fun julọ ni bi on ba duro bẹ̃: emi pẹlu si rò pe mo li Ẹmi Ọlọrun.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
I. Kor 7: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.