Nitori alabaṣiṣẹpọ pẹlu Ọlọrun li awa: ọgbà Ọlọrun ni nyin, ile Ọlọrun ni nyin. Gẹgẹ bi ore-ọfẹ Ọlọrun ti a fifun mi, bi ọlọ́gbọn ọ̀mọ̀lé, mo ti fi ipilẹ sọlẹ, ẹlomiran si nmọ le e. Ṣugbọn ki olukuluku kiyesara bi o ti nmọ le e. Nitori ipilẹ miran ni ẹnikan kò le fi lelẹ jù eyiti a ti fi lelẹ lọ, ti iṣe Jesu Kristi. Njẹ bi ẹnikẹni ba mọ wura, fadaka, okuta iyebiye, igi, koriko, akekù koriko le ori ipilẹ yi; Iṣẹ́ olukuluku enia yio hàn. Nitori ọjọ na yio fi i hàn, nitoripe ninu iná li a o fi i hàn; iná na yio si dán iṣẹ olukuluku wò irú eyiti iṣe. Bi iṣẹ ẹnikẹni ti o ti ṣe lori rẹ̀ ba duro, on ó gbà ère. Bi iṣẹ ẹnikẹni ba jóna, on a pàdanù: ṣugbọn on tikararẹ̀ li a o gbalà, ṣugbọn bi ẹni nlà iná kọja. Ẹnyin kò mọ̀ pe tẹmpili Ọlọrun li ẹnyin iṣe, ati pe Ẹmí Ọlọrun ngbe inu nyin? Bi ẹnikan bá ba tẹmpili Ọlọrun jẹ, on ni Ọlọrun yio parun; nitoripe mimọ́ ni tẹmpili Ọlọrun, eyiti ẹnyin jẹ.
Kà I. Kor 3
Feti si I. Kor 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Kor 3:9-17
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò