I. Kro 3

3
Àwọn Ọmọ Dafidi Ọba
1WỌNYI li awọn ọmọ Dafidi, ti a bi fun u ni Hebroni; akọbi Amnoni, lati ọdọ Ahinoamu ara Jesreeli; ekeji Danieli, lati ọdọ Abigaili ara Karmeli;
2Ẹkẹta, Absalomu ọmọ Maaka ọmọbinrin Talmai ọba Gesuri; ẹkẹrin, Adonijah ọmọ Haggiti.
3Ẹkarun, Ṣefatiah lati ọdọ Abitali; ẹkẹfa Itreamu lati ọdọ Ẹgla aya rẹ̀.
4Awọn mẹfa wọnyi li a bi fun u ni Hebroni; nibẹ li o si jọba li ọdun meje on oṣù mẹfa: ati ni Jerusalemu li o jọba li ọdun mẹtalelọgbọn.
5Wọnyi li a si bi fun u ni Jerusalemu; Ṣimea, ati Ṣobabu, ati Natani, ati Solomoni, mẹrin, lati ọdọ Batṣua ọmọbinrin Ammieli:
6Abhari pẹlu, ati Eliṣama, ati Elifeleti,
7Ati Noga, ati Nefegi, ati Jafia,
8Ati Eliṣama, ati Eliada, ati Elifeleti mẹsan.
9Wọnyi ni gbogbo awọn ọmọ Dafidi, laika awọn ọmọ àle rẹ̀, ati Tamari arabinrin wọn.
Ìran Solomoni Ọba
10Ọmọ Solomoni si ni Rehoboamu, Abia ọmọ rẹ̀, Asa ọmọ rẹ̀, Jehoṣafati ọmọ rẹ̀.
11Joramu ọmọ rẹ̀, Ahasiah ọmọ rẹ̀, Joaṣi ọmọ rẹ̀,
12Amasiah ọmọ rẹ̀, Asariah ọmọ rẹ̀, Jotamu ọmọ rẹ̀,
13Ahasi ọmọ rẹ̀, Hesekiah ọmọ rẹ̀, Manasse ọmọ rẹ̀,
14Amoni ọmọ rẹ̀, Josiah ọmọ rẹ̀.
15Ati awọn ọmọ Josiah; akọbi Johanani, ekeji Jehoiakimu, ẹkẹta Sedekiah, ẹkẹrin Ṣallumu.
16Ati awọn ọmọ Jehoiakimu: Jekoniah ọmọ rẹ̀, Sedekiah ọmọ rẹ̀,
Àwọn Ìran Jehoiakini
17Ati awọn ọmọ Jekoniah; Assiri, Salatieli ọmọ rẹ̀.
18Malkiramu pẹlu, ati Pedaiah, ati Ṣenasari, Jekamiah, Hoṣama ati Nehabiah,
19Ati awọn ọmọ Pedaiah; Serubbabeli; ati Ṣimei; ati awọn ọmọ Serubbabeli; Meṣullamu, ati Hananiah, ati Ṣelomiti arabinrin wọn:
20Ati Haṣuba, ati Oheli, ati Berekiah, ati Hasadiah, Juṣab-hesedi, marun.
21Ati awọn ọmọ Hananiah; Pelatiah, ati Jesaiah: awọn ọmọ Refaiah, awọn ọmọ Arnani, awọn ọmọ Obadiah, awọn ọmọ Ṣekaniah.
22Ati awọn ọmọ Ṣekaniah; Ṣemaiah; ati awọn ọmọ Ṣemaiah; Hettuṣi, ati Igeali, ati Bariah, ati Neariah, ati Ṣafati, mẹfa.
23Ati awọn ọmọ Neariah; Elioenai, ati Hesekiah, ati Asrikamu, meta.
24Ati awọn ọmọ Elioenai ni, Hodaiah, ati Eliaṣibu, ati Pelaiah, ti Akkubu, ati Johanani, ati Dalaiah, ati Anani, meje.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kro 3: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa