I. Kro 28:2-10

I. Kro 28:2-10 YBCV

Nigbana ni Dafidi ọba dide duro li ẹsẹ rẹ̀, o si wipe, Ẹ gbọ́ ti emi, ẹnyin arakunrin mi ati enia mi: emi fẹ li ọkàn mi lati kọ́ ile isimi kan fun apoti ẹri majẹmu Oluwa, ati fun itisẹ Ọlọrun wa, mo si ti mura tan fun kikọ́le na: Ṣugbọn Ọlọrun sọ fun mi pe, Iwọ kò gbọdọ kọ́ ile fun orukọ mi, nitori ologun ni iwọ, o si ti ta ẹ̀jẹ silẹ. Oluwa Ọlọrun Israeli si yàn mi lati inu gbogbo ile baba mi lati jẹ ọba lori Israeli lailai: nitori ti o ti yàn Juda li olori; ati ninu ile Juda, ile baba mi: ati larin awọn ọmọ baba mi o fẹ mi lati jẹ ọba gbogbo Israeli. Ati ninu gbogbo ọmọ mi ọkunrin (nitori ti Oluwa ti fun mi li ọmọkunrin pupọ), o ti yàn Solomoni ọmọ mi lati joko lori itẹ ijọba Oluwa lori Israeli. On si wi fun mi pe, Solomoni ọmọ rẹ, on yio kọ́ ile mi ati agbala mi: nitori emi ti yàn a li ọmọ mi, emi o si jẹ baba fun u. Pẹlupẹlu emi o fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ lailai, bi o ba murale lati ṣe ofin mi ati idajọ mi bi li oni yi. Njẹ nisisiyi li oju gbogbo Israeli ijọ enia Oluwa, ati li eti Ọlọrun wa, ẹ ma pamọ́ ki ẹ si ma ṣafẹri gbogbo ofin Oluwa Ọlọrun nyin: ki ẹ le ni ilẹ rere yi, ki ẹ si le fi i silẹ li ogún fun awọn ọmọ nyin lẹhin nyin lailai. Ati iwọ, Solomoni ọmọ mi, mọ̀ Ọlọrun baba rẹ, ki o si fi aiya pipé ati fifẹ ọkàn sìn i: nitori Oluwa a ma wá gbogbo aiya, o si mọ̀ gbogbo ete ironu: bi iwọ ba ṣafẹri rẹ̀, iwọ o ri i; ṣugbọn bi iwọ ba kọ̀ ọ silẹ on o ta ọ nù titi lai. Wò o nisisiyi: nitori Oluwa ti yàn ọ lati kọ́ ile kan fun ibi mimọ́, mura le, ki iwọ si ṣe e.