I. Kro 27

27
Àwọn Ológun ati Ètò Òṣèlú
1NJẸ awọn ọmọ Israeli nipa iye wọn, eyini ni, awọn olori baba, ati awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati ọrọrun, ati awọn ijoye wọn ti nsìn ọba ni olukuluku ọ̀na li ẹgbẹgbẹ, ti nwọle ti si njade li oṣoṣù ni gbogbo oṣù ọdun, jẹ́ ẹgbã mejila.
2Lori ẹgbẹ kini ti oṣù kini ni Jaṣobeamu ọmọ Sabdieli: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
3Ninu awọn ọmọ Peresi on ni olori fun gbogbo awọn olori ogun ti oṣù ekini.
4Ati lori ẹgbẹ ti oṣù keji ni Dodai ara Ahohi, ati ẹgbẹ tirẹ̀; Mikloti pẹlu nṣe balogun: ẹgbã mejila li o wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀ pẹlu.
5Olori ogun kẹta fun oṣù kẹta ni Benaiah ọmọ Jehoiada alufa, olori kan: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
6Eyini ni Benaiah na, akọni enia, ninu awọn ọgbọ̀n, o si jẹ olori awọn ọgbọ̀n: Amisabadi ọmọ rẹ̀ si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
7Olori ogun kẹrin fun oṣù kẹrin ni Asaheli arakunrin Joabu, ati Sebadiah ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
8Olori ogun karun fun oṣù karun ni Ṣamhuti ara Israhi: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
9Olori ogun kẹfa fun oṣù kẹfa ni Ira ọmọ Ikkeṣi ara Tekoi: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
10Olori ogun keje fun oṣù keje ni Heleṣi ara Peloni, ninu awọn ọmọ Efraimu: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
11Olori ogun kẹjọ fun oṣù kẹjọ ni Sibbekai ara Huṣati ti awọn ara Sarehi: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
12Olori ogun kẹsan fun oṣù kẹsan ni Abieseri ara Anatoti ti awọn ara Benjamini: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
13Olori ogun kẹwa fun oṣù kẹwa ni Maharai ara Netofa, ti awọn ara Sarehi: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
14Olori ogun kọkanla fun oṣù kọkanla ni Benaiah ara Peratoni, ti awọn ọmọ Efraimu: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
15Olori ogun kejila fun oṣù kejila ni Heldai ara Netofa, ti Otnieli: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
Ètò Àkóso Àwọn Ẹ̀yà Israẹli
16Ati lori awọn ẹ̀ya Israeli: ijoye lori awọn ọmọ Reubeni ni Elieseri ọmọ Sikri: lori awọn ọmọ Simeoni, Ṣefatiah ọmọ Maaka:
17Lori awọn ọmọ Lefi, Haṣabiah ọmọ Kemueli: lori awọn ọmọ Aaroni, Sadoku:
18Lori Juda, Elihu, ọkan ninu awọn arakunrin Dafidi: lori Issakari, Omri ọmọ Mikaeli:
19Lori Sebuloni, Iṣmaiah ọmọ Obadiah: lori Naftali, Jerimoti ọmọ Asrieli:
20Lori awọn ọmọ Efraimu, Hoṣea ọmọ Asasiah: lori àbọ ẹ̀ya Manasse, Joeli ọmọ Pedaiah.
21Lori àbọ ẹ̀ya Manasse ni Gileadi, Iddo ọmọ Sekariah: lori Benjamini, Jaasieli ọmọ Abneri.
22Lori Dani, Asareeli ọmọ Jerohamu Awọn wọnyi li olori awọn ẹ̀ya Israeli.
23Ṣugbọn Dafidi kò ka iye awọn ti o wà lati ogun ọdun ati awọn ti kò to bẹ̃; nitori ti Oluwa ti wipe on o mu Israeli pọ̀ si i bi irawọ oju ọrun.
24Joabu ọmọ Seruiah bẹ̀rẹ si ikà wọn, ṣugbọn kò kà wọn tan, nitori ibinu ṣubu lu Israeli nitori na; bẹ̃ni a kò fi iye na sinu iwe Kronika ti Dafidi ọba.
25Lori awọn iṣura ọba ni Asmafeti ọmọ Adieli wà: ati lori iṣura oko, ni ilu, ati ni ileto, ati ninu odi ni Jonatani ọmọ Ussiah wà:
26Ati lori awọn ti nro oko, lati ma ro ilẹ ni Esri ọmọ Kelubi wà:
27Ati lori awọn ọgba-àjara ni Ṣimei ara Ramoti wà: lori eso ọgba-àjara fun iṣura ati ọti-waini ni Sabdi ọmọ Ṣifmi wà:
28Ati lori igi-olifi, ati igi-sikamore ti mbẹ ni pẹ̀tẹlẹ ni Baal-hanani ara Gederi wà; ati lori iṣura ororo ni Joaṣi wà.
29Ati lori awọn agbo malu ti njẹ̀ ni Ṣaroni ni Ṣitrai ara Ṣaroni wà: ati lori agbo malu ti o wà li afonifoji ni Ṣafati ọmọ Adlai wà:
30Ati lori ibakasiẹ ni Obili ara Iṣmaeli wà: ati lori abo kẹtẹkẹtẹ ni Jehodaiah ara Meronoti wà:
31Ati lori agbo agutan ni Jasisi ara Hageri wà. Gbogbo awọn wọnyi ni ijoye ohun ini ti iṣe ti Dafidi ọba.
Àwọn Olùdámọ̀ràn Dafidi Ọba
32Jonatani ẹgbọn Dafidi pẹlu ni ìgbimọ ọlọgbọ́n enia ati akọwe: ati Jehueli ọmọ Hakmoni wà pẹlu awọn ọmọ ọba.
33Ahitofeli si jẹ ìgbimọ ọba: ati Huṣai ara Arki ni ọrẹ ọba.
34Ati lẹhin Ahitofeli ni Jehoiada ọmọ Benaiah, ati Abiatari: Joabu si ni arẹ-balogun ogun ọba.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kro 27: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀