I. Kro 26

26
Àwọn Aṣọ́nà Tẹmpili
1NITI ipin awọn adena: niti awọn ọmọ Kosa ni Meṣelemiah ọmọ Kore, ninu awọn ọmọ Asafu.
2Ati awọn ọmọ Meṣelemiah ni Sekariah akọbi, Jediaeli ekeji, Sebadiah ẹkẹta, Jatnieli ẹkẹrin,
3Elamu ẹkarun, Johanani ẹkẹfa, Elioenai ekeje.
4Awọn ọmọ Obed-Edomu si ni Ṣemaiah akọbi, Jehosabadi ekeji, Joa ẹkẹta, ati Sakari ẹkẹrin, ati Netaneeli ẹkarun,
5Ammieli ẹkẹfa, Issakari ekeje, Peulltai ẹkẹjọ: Ọlọrun sa bukún u.
6Ati fun Ṣemaiah ọmọ rẹ̀ li a bi awọn ọmọ ti nṣe olori ni ile baba wọn: nitori alagbara akọni enia ni nwọn.
7Awọn ọmọ Ṣemaiah; Otni, ati Refaeli, ati Obedi, Elsabadi, arakunrin ẹniti iṣe alagbara enia, Elihu, ati Semakiah.
8Gbogbo wọnyi ti inu awọn ọmọ Obed-Edomu, ni: awọn, ati awọn ọmọ wọn, ati awọn arakunrin wọn, akọni enia ati alagbara fun ìsin na, jẹ mejilelọgọta lati ọdọ Obed-Edomu;
9Meṣelemiah si ni awọn ọmọ ati arakunrin, alagbara enia, mejidilogun.
10Hosa pẹlu, ninu awọn ọmọ Merari, ni ọmọ; Simri olori (nitori bi on kì iti iṣe akọbi ṣugbọn baba rẹ̀ fi jẹ olori),
11Hilkiah ekeji, Tebaliah ẹkẹta, Sekariah ẹkẹrin: gbogbo awọn ọmọ ati awọn arakunrin Hosa jẹ mẹtala.
12Ninu awọn wọnyi ni ipin awọn adena, ani ninu awọn olori ọkunrin, ti nwọn ni iṣẹ gẹgẹ bi awọn arakunrin wọn, lati ṣe iranṣẹ ni ile Oluwa.
13Nwọn si ṣẹ keké, bi ti ẹni-kekere bẹ̃ni ti ẹni-nla, gẹgẹ bi ile baba wọn, fun olukuluku ẹnu-ọ̀na.
14Iṣẹ keké iha ila-õrun bọ̀ sọdọ Ṣelemiah. Nigbana ni nwọn ṣẹ keké fun Sekariah ọmọ rẹ̀, ọlọgbọ́n igbimọ; iṣẹ keké rẹ̀ si bọ si iha ariwa.
15Sọdọ Obed-Edomu niha gusù; ati sọdọ awọn ọmọ rẹ̀ niha ile Asuppimu (yara iṣura).
16Ti Suppimu ati Hosa niha iwọ-õrun li ẹnu-ọ̀na Ṣalleketi, nibi ọ̀na igòke lọ, iṣọ kọju si iṣọ.
17Niha ìla-õrùn awọn ọmọ Lefi mẹfa (nṣọ), niha ariwa mẹrin li ojojumọ, niha gusù mẹrin li ojojumọ, ati ninu Asuppimu (ile iṣura) mejimeji.
18Ni ibasa niha iwọ-õrùn, mẹrin li ọ̀na igòke-lọ ati meji ni ibasa.
19Wọnyi ni ipin awọn adena lati inu awọn ọmọ Kore, ati lati inu awọn ọmọ Merari.
Àwọn Iṣẹ́ Mìíràn ninu Tẹmpili
20Lati inu awọn ọmọ Lefi, Ahijah li o wà lori iṣura ile Ọlọrun, ati lori iṣura nkan wọnni ti a yà si mimọ́.
21Awọn ọmọ Laadani; awọn ọmọ Laadani ara Gerṣoni, awọn olori baba, ani ti Laadani ara Gerṣoni ni Jehieli.
22Awọn ọmọ Jehieli; Setamu, ati Joeli arakunrin rẹ̀, ti o wà lori iṣura ile Oluwa.
23Ninu ọmọ Amramu, ati ọmọ Ishari, ara Hebroni, ati ọmọ Ussieli:
24Ati Ṣebueli ọmọ Gerṣomu, ọmọ Mose, ni onitọju iṣura.
25Ati awọn arakunrin rẹ̀ nipa Elieseri, Rehabiah ọmọ rẹ̀, ati Jesaiah ọmọ rẹ̀, ati Joramu, ọmọ rẹ̀, ati Sikri ọmọ rẹ̀, ati Ṣelomiti ọmọ rẹ̀.
26Ṣelomiti yi ati awọn arakunrin rẹ̀ li o wà lori iṣura ohun iyà-si-mimọ́, ti Dafidi ọba ati awọn olori baba, awọn ijoye lori ẹgbẹgbẹrun, ati ọrọrun, ati awọn olori ogun ti yà-si-mimọ́.
27Lati inu ikogun ti a kó li ogun, ni nwọn yà si mimọ́ lati ma fi ṣe itọju ile Oluwa.
28Ati gbogbo eyiti Samueli, ariran, ati Saulu, ọmọ Kiṣi, ati Abneri ọmọ Neri, ati Joabu ọmọ Seruiah, yà si mimọ́; gbogbo ohun ti a ba ti yà si mimọ́, ohun na mbẹ li ọwọ Ṣelomiti, ati awọn arakunrin rẹ̀.
Iṣẹ́ Àwọn Ọmọ Lefi Yòókù
29Ninu awọn ọmọ Ishari, Kenaniah ati awọn ọmọ rẹ̀ li o jẹ ijoye ati onidajọ fun iṣẹ ilu lori Israeli.
30Ninu awọn ọmọ Hebroni, Hasabiah ati awọn arakunrin rẹ̀, awọn akọni enia, ẽdẹgbẹsan li awọn alabojuto Israeli nihahin Jordani niha iwọ-õrun, fun gbogbo iṣẹ Oluwa, ati fun ìsin ọba.
31Ninu awọn ọmọ Hebroni ni Jerijah olori, ani ninu awọn ọmọ Hebroni, gẹgẹ bi idile ati iran awọn baba rẹ̀. Li ogoji ọdun ijọba Dafidi, a wá wọn, a si ri ninu wọn, awọn alagbara akọni enia ni Jaseri ti Gileadi.
32Ati awọn arakunrin rẹ̀, awọn akọni enia, jẹ ẹgbã o le ẽdẹgbẹrin: gbogbo wọn jẹ awọn olori baba ti Dafidi ọba fi ṣe olori lori awọn ọmọ Rubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, fun gbogbo ọ̀ran ti Ọlọrun ati ti ọba.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kro 26: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀