I. Kro 25

25
Àwọn Akọrin Inú Tẹmpili
1PẸLUPẸLU Dafidi ati awọn olori ogun yà ninu awọn ọmọkunrin Asafu, ati Hemani, ati Jedutuni, fun ìsin yi, awọn ẹniti o ma fi duru ati psalteri, ati kimbali kọrin: ati iye awọn oniṣẹ gẹgẹ bi ìsin wọn jẹ:
2Ninu awọn ọmọ Asafu, Sakkuri, ati Josefu, ati Netaniah, ati Asarela, awọn ọmọ Asafu labẹ ọwọ Asafu, ti o kọrin gẹgẹ bi aṣẹ ọba.
3Ti Jedutuni: awọn ọmọ Jedutuni; Gedaliah, ati Seri, ati Jeṣaiah, Haṣabiah, ati Mattitiah, ati Ṣimei, mẹfa, labẹ ọwọ baba wọn Jedutuni, ẹniti o fi duru kọrin, lati ma dupẹ fun ati lati ma yìn Oluwa.
4Ti Hemani: awọn ọmọ Hemani; Bukkiah, Mattaniah, Ussieli, Ṣebueli, ati Jerimotu, Hananiah, Hanani, Eliata, Giddalti, ati Romamtieseri, Joṣbekaṣa, Malloti, Hotiri, Mahasiotu:
5Gbogbo awọn wọnyi li awọn ọmọ Hemani, woli ọba ninu ọ̀rọ Ọlọrun, lati ma gbé iwo na soke. Ọlọrun si fun Hemani li ọmọkunrin mẹrinla ati ọmọbinrin mẹta.
6Gbogbo awọn wọnyi li o wà labẹ ọwọ baba wọn, fun orin ile Oluwa, pẹlu kimbali, psalteri ati duru, fun ìsin ile Ọlọrun: labẹ ọwọ ọba, ni Asafu, Jedutuni, ati Hemani wà.
7Bẹ̃ni iye wọn, pẹlu awọn arakunrin wọn ti a kọ́ li orin Oluwa, ani gbogbo awọn ti o moye, jasi ọrinlugba o le mẹjọ.
8Nwọn si ṣẹ keké fun iṣẹ; gbogbo wọn bakanna bi ti ẹni-kekere bẹ̃ni ti ẹni-nla, ti olukọ bi ti ẹniti a nkọ́.
9Iṣẹkeké ekini si jade wá fun Asafu si Josefu: ekeji si Gedaliah, ẹniti on pẹlu awọn arakunrin rẹ̀ ati awọn ọmọ rẹ̀, jẹ mejila:
10Ẹkẹta si Sakkuri, awọn ọmọ rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
11Ẹkẹrin si Isri, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
12Ẹkarun si Netaniah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
13Ẹkẹfa si Bukkiah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
14Ekeje si Jeṣarela, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
15Ẹkẹjọ si Jeṣaiah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
16Ẹkẹsan si Mattaniah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
17Ẹkẹwa si Ṣimei, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
18Ẹkọkanla si Asareeli, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
19Ekejila si Haṣabiah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
20Ẹkẹtala si Ṣubaeli, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
21Ẹkẹrinla si Mattitiah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
22Ẹkẹ̃dogun si Jeremoti, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
23Ẹkẹrindilogun si Hananiah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
24Ẹkẹtadilogun si Joṣbekaṣa awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
25Ekejidilogun si Hanani, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
26Ẹkọkandilogun si Malloti, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
27Ogun si Eliata, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
28Ẹkọkanlelogun si Hotiri, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
29Ekejilelogun si Giddalti, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
30Ẹkẹtalelogun si Mahasioti, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
31Ẹkẹrinlelogun si Romamti-eseri, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kro 25: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀