Nigbana ni angeli Oluwa na paṣẹ fun Gadi lati sọ fun Dafidi pe, ki Dafidi ki o gòke lọ ki o si tẹ pẹpẹ kan fun Oluwa, ni ilẹ ipaka Ornani, ara Jebusi. Dafidi si gòke lọ nipa ọ̀rọ Gadi, ti o sọ li orukọ Oluwa. Ornani si yipada, o si ri angeli na; ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹrin pẹlu rẹ̀ pa ara wọn mọ́. Njẹ Ornani npa ọka lọwọ. Bi Dafidi si ti de ọdọ Ornani, Ornani si wò, o si ri Dafidi, o si ti ibi ilẹ ipaka rẹ̀ jade, o si wolẹ, o dojubolẹ fun Dafidi. Dafidi si wi fun Ornani pe, Fun mi ni ibi ipaka yi, ki emi ki o le tẹ pẹpẹ kan nibẹ fun Oluwa; iwọ o si fi fun mi ni iye owo rẹ̀ pipe; ki a le da ajakalẹ arun duro lọdọ awọn enia. Ornani si wi fun Dafidi pe, Mu u fun ra rẹ, si jẹ ki oluwa mi ọba ki o ṣe eyiti o dara loju rẹ̀: wò o mo fi awọn malu pẹlu fun ẹbọ-ọrẹ-sisun, ati ohun èlo ipaka fun igi, ati ọka fun ọrẹ onjẹ; mo fi gbogbo rẹ̀ fun ọ. Dafidi ọba si wi fun Ornani pe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn emi a rà a ni iye owo rẹ̀ pipe nitõtọ, nitoriti emi kì o mu eyi ti iṣe tirẹ fun Oluwa, bẹ̃ni emi kì o ru ẹbọ-ọrẹ sisun laiṣe inawo. Bẹ̃ni Dafidi fi ẹgbẹta ṣekeli wura nipa iwọn fun Ornani fun ibẹ na. Dafidi si tẹ pẹpẹ kan nibẹ fun Oluwa, o si ru ẹbọ ọrẹ-sisun ati ẹbọ ọpẹ, o si kepe Oluwa; on si fi iná da a li ohùn lati ọrun wá lori pẹpẹ ẹbọ-ọrẹ sisun na. Oluwa si paṣẹ fun angeli na; on si tun tẹ ida rẹ̀ bọ inu akọ rẹ̀. Li akokò na nigbati Dafidi ri pe Oluwa ti da on li ohùn ni ibi ilẹ-ipaka Ornani, ara Jebusi, o si rubọ nibẹ. Nitori agọ Oluwa ti Mose pa li aginju, ati pẹpẹ ọrẹ sisun, mbẹ ni ibi giga ni Gibeoni li akokò na. Ṣugbọn Dafidi kò le lọ siwaju rẹ̀ lati bere lọwọ Ọlọrun: nitoriti ẹ̀ru idà angeli Oluwa na ba a.
Kà I. Kro 21
Feti si I. Kro 21
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Kro 21:18-30
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò