I. Kro 15

15
Ìmúra láti Gbé Àpótí Majẹmu Pada
1DAFIDI si kọ́ ile fun ara rẹ̀ ni ilu Dafidi, o si pese ipò kan fun apoti ẹri Ọlọrun, o si pa agọ kan fun u.
2Nigbana ni Dafidi wipe, Ẹnikan kò yẹ lati rù apoti ẹri Ọlọrun bikoṣe awọn ọmọ Lefi; nitori awọn ni Oluwa ti yàn lati ma gbé apoti ẹri Ọlọrun, ati lati ma ṣe iranṣẹ fun u titi lai.
3Dafidi si ko gbogbo Israeli jọ si Jerusalemu, lati gbé apoti ẹri Oluwa gòke lọ si ipò rẹ̀ ti o ti pese fun u.
4Dafidi si pè awọn ọmọ Aaroni, ati awọn ọmọ Lefi jọ.
5Ninu awọn ọmọ Kohati; Urieli olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ ọgọfa:
6Ninu awọn ọmọ Merari; Asaiah olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ igba o le ogun:
7Ninu awọn ọmọ Gerṣomu; Joeli olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ ãdoje:
8Ninu awọn ọmọ Elisafani; Ṣemaiah olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ igba.
9Ninu awọn ọmọ Hebroni; Elieli olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ ọgọrin:
10Ninu awọn ọmọ Ussieli; Aminadabu olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ mejilelãdọfa.
11Dafidi si ranṣẹ pè Sadoku ati Abiatari awọn alufa; ati awọn ọmọ Lefi, Urieli, Asaiah, ati Joeli, Ṣemaiah, ati Elieli, ati Aminadabu;
12O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li olori awọn baba awọn ọmọ Lefi: ẹ ya ara nyin si mimọ́, ẹnyin ati awọn arakunrin nyin, ki ẹnyin ki o le gbé apoti ẹri Oluwa Ọlọrun Israeli gòke lọ si ibi ti mo ti pèse fun u.
13Nitoriti ẹnyin kò rù u li akọṣe, ni Oluwa Ọlọrun wa fi ṣe ẹ̀ya si wa li ara, nitori awa kò wá a bi o ti yẹ.
14Bẹ̃ li awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi ya ara wọn si mimọ́ lati gbe apoti ẹri Oluwa Ọlọrun Israeli gòke wá.
15Awọn ọmọ Lefi si rù apoti ẹri Ọlọrun bi Mose ti pa a li aṣẹ gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, nwọn fi ọpa rù u li ejika wọn.
16Dafidi si wi fun olori awọn ọmọ Lefi pe ki nwọn yàn awọn arakunrin wọn, awọn akọrin pẹlu ohun èlo orin, psalteri ati duru, ati kimbali; ti ndún kikan ti o si nfi ayọ gbé ohùn soke.
17Bẹ̃ li awọn ọmọ Lefi yan Hemani ọmọ Joeli; ati ninu awọn arakunrin rẹ̀, Asafu ọmọ Berekiah; ati ninu awọn ọmọ Merari arakunrin wọn, Etani ọmọ Kuṣaiah;
18Ati pẹlu wọn awọn arakunrin wọn li ọwọ́ keji; Sekariah, Beni, ati Jaasieli, ati Ṣemiramotu, ati Jehieli, ati Unni, Eliabu, ati Benaiah, ati Maaseiah, ati Obed-Edomu, ati Jeieli awọn adena.
19Awọn akọrin si ni Hemani, Asafu, ati Etani, ti awọn ti kimbali ti ndun kikan;
20Ati Sekariah, ati Asieli, ati Ṣemiramotu, ati Jelieli, ati Unni, ati Eliabu, ati Maaseiah, ati Benaiah, ti awọn ti psaltiri olohùn òke;
21Ati Mattitiah, ati Elifeleti, ati Mikneiah, lati fi duru olokun mẹjọ ṣaju orin.
22Ati Kenaniah, olori awọn ọmọ Lefi ni ọ̀ga orin: on ni nkọni li orin, nitoriti o moye rẹ̀.
23Ati Berekiah, ati Elkana li awọn adena fun apoti ẹri na.
24Ati Ṣebaniah, ati Jehoṣafati, ati Netaneeli, ati Amasai, ati Sekariah, ati Benaiah, ati Elieseri, awọn alufa, li o nfun ipè niwaju apoti ẹri Ọlọrun: ati Obed-Edomu, ati Jehiah li awọn adena fun apoti ẹri na.
Gbígbé Àpótí Majẹmu Lọ sí Jerusalẹmu
(II. Sam 6:12-22)
25Bẹ̃ni Dafidi ati awọn agbagba Israeli, ati awọn olori ẹgbẹgbẹrun, lọ lati gbe apoti ẹri majẹmu Oluwa jade ti ile Obed-Edomu gòke wá pẹlu ayọ̀.
26O si ṣe, nigbati Ọlọrun ràn awọn ọmọ Lefi lọwọ ti o rù apoti ẹri majẹmu Oluwa, ni nwọn fi malu meje ati àgbo meje rubọ.
27Dafidi si wọ̀ aṣọ igunwa ọ̀gbọ daradara, ati gbogbo awọn ọmọ Lefi ti nrù apoti ẹri na, ati awọn akọrin, ati Kenaniah olori orin pẹlu awọn akọrin: efodu ọ̀gbọ si wà lara Dafidi.
28Bayi ni gbogbo Israeli gbé apoti ẹri majẹmu Oluwa gòke wá pẹlu iho ayọ̀, ati iró fère, ati pẹlu ipè, ati kimbali, psalteri ati duru si ndún kikankikan.
29O si ṣe bi apoti ẹri majẹmu Oluwa na ti de ilu Dafidi ni Mikali ọmọ Saulu obinrin yọju wode ni fèrese, o ri Dafidi ọba njó, o si nṣire; o si kẹgan rẹ̀ li ọkàn rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kro 15: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa